Tiyanu-tiyanu layẹyẹ ọjọ ibi airotẹlẹ ti awọn akẹkọọ-jade nile ẹkọ girama ti Rẹmọ, iyẹn Remo Secondary School laaarin ọdun 1988 si 1993 ṣe jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited, Aarẹ Adetola EmmanuelKing.
Inu ọgba ile itura Marriott to wa niluu Eko, ipinlẹ Eko ni ayẹyẹ ọjọ ibi airotẹlẹ naa ti waye, nibi ti gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ akẹkọọ-jade naa ti peju.
AWIKONKO gbọ pe yatọ si awọn ọmọ ẹgbẹ naa to wa ni Naijiria lọwọlọwọ, awọn to tun wa loke okun naa darapọ lati kopa, nipa wiwo bo ṣe n lọ lori ikanni ayelujara.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn sọ pe inu oṣu Kinni, ọdun yii lawọn ọmọ ẹgbẹ naa, labẹ aburada ti wọn pe ni Remo Secondary School Old Students Association (RSSOSA) ti n gbaradi lati ṣayẹyẹ ọhun.
Gbogbo erongba wọn la gbọ pe o n ja si pabo, pẹlu bi Aarẹ EmmanuelKing ko ṣe raaye, bo tilẹ jẹ pe ko mọ ohunkohun nipa rẹ tẹlẹ.
A gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ RSSOSA yii lẹdi apo papọ pẹlu iyawo Aarẹ Adetọla EmmanuelKing lati le jẹ ki ayẹyẹ ọhun le ṣee ṣe.
Aarẹ EmmanuelKing ni aarẹ ẹgbẹ RSSOSA ti ọdun 88/93 yii, to si ti kopa to jọju, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Ọkunrin naa lọ fun ara rẹ nisinmi nile itura Marriott naa ni, ko to di pe awọn ọmọ ẹgbẹ yii lọ ka a mọbẹ lati ṣayẹyẹ ọjọ ibi airotẹlẹ naa fun.
Pẹlu iyalẹnu nla ni Aarẹ EmmanuelKing fi bu sẹkun ayọ, nitori to sọ pe oun ko tiẹ figba kan ro o ri wi pe iru nnkan bẹẹ le ṣẹlẹ.
Oriṣiriṣi ẹbun olowo iyebiye to to miliọnu naira ni awọn ọmọ ẹgbẹ yii fi ta Aarẹ wọn lọrẹ, ti wẹjẹ-wẹmu tun ṣẹlẹ lara-ọtọ.
Lara awọn ọmọ naa to darapọ lori itakun ayelujara lati United Kingdom, Canada, Amẹrika la ti ri Segun Osho, Rev. Fr. Oshitimehin, Sade Odesanya, Akeem Elegbeji, Gboyega Solarin, Johnson Olumuyiwa Sanya, ati Tope Otunba.
Awọn miran ni Semeton Amosu, Yemisi Olowu, Bukky Alli, Bunmi Ojutialayo, Bolaji Desalu, Wasiu Talabi, Azeez Awolaja, Jimmy Adetayo, ati Bisoye Sholuade, ti awọn naa tun fi ẹbun ti wọn ranṣẹ.
Gomina ẹgbẹ naa, Onimọ-ẹrọ Bola Owolabi Oladeinde ni wọn lo ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe wọn ṣe aṣeyọri nla to pada waye.
Nigba toun naa n fi omije ayọ sọrọ, alaṣẹ Adron Homes sọ pe oun ko figba kan la ala rẹ ri wi pe iru nnkan bẹẹ le waye, to si lo mu ori oun wu lọpọlọpọ.
Bo ṣe dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ baa, bẹẹ naa lo tun dupẹ lọwọ iyawo rẹ, ẹni to duro ṣinṣin lati rii pe ilọsiwaju n de ba oun ni gbogbo igba.
No comments:
Post a Comment