Ẹ fura lori ayederu iranlọwọ fawọn agbẹ ti wọn n gbe kaakiri - Ijọba Kwara pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 17, 2025

Ẹ fura lori ayederu iranlọwọ fawọn agbẹ ti wọn n gbe kaakiri - Ijọba Kwara pariwo sita

 
Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbudlRahman AbdulRazaq ti ke gbajare sawọn araalu, paapaa awọn agbẹ wi pe ki wọn ma ṣe lugbadi ayederu eto anfaani kan tawọn kan n gbe kaakiri lati fi ṣe iranlọwọ fawọn agbẹ.
 
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ to n ri sọrọ eto iṣẹ agbẹ ati idagbasoke igberiko nipinlẹ naa fi sita, ni wọn ti jẹ k o di mimọ pe awọn ko lọwọ si atẹjiṣẹ ti wọn fi n ranṣẹ kaakiri ikanni wasaapu, ati pe awọn oni jibiti lo wa nidi rẹ.
 
Ileeṣẹ naa sọ pe ''A ti ṣakiyesi atẹjiṣẹ kan ti wọn n pin kaakiri ori ikanni ayelujara, paapaa wasaapu, leyi ti wọn fi n sọ fawọn agbẹ lati ati awọn to ni ileeṣẹ ati okoowo to jẹ mọ agbẹ lati fi idanimọ wọn ranṣẹ tabi ki wọn kopa ninu eto iforukọsilẹ fun anfaani kan ti wọn lọ mọ ijọba lẹsẹ, nipa ẹyawo tabi iranwọ.''
 
Awọn alakoso ileeṣẹ naa sọ pe awọn ko ni ibaṣepọ pẹlu ileeṣẹ tabi ajọ kankan ati paapaa ẹgbẹ kankan, eyi ti wọn ko le fidi rẹ mulẹ nipa gbigba orukọ ati idanimọ awọn eeyan, bi eyi ti wọn n ṣe kaakiri lasiko yii.

''Asiko ẹlẹgẹ la wa yii ninu onka iṣẹ agbẹ, ati pe o ye wa nipa bi ọpọ awọn agbẹ ṣe n foju sọna fun oniruuru eto iranwọ ati anfaani idanilẹkọọ. Ṣugbọn, o ṣeni laanu wi pe asiko yii kan naa lawọn onijibiti ati alọnilọwọgba naa n wa ọna lati lu awọn eeyan ni jibiti,'' atẹjade ọhun fidi rẹ mulẹ.

Wọn wa rọ araalu, awọn agbẹ ati awọn to ni okoowo tabi ileeṣẹ to n ri sọrọ agbẹ, ati paapaa ẹgbẹ tabi ẹgbẹ alajẹṣẹku nipa iṣẹ agbẹ kaakiri ipinlẹ naa lati ṣọra fun awọn oni jibiti ọhun, ati pe ki wọn ṣewadi daadaa, ki wọn ma ba a ko sọwọ awọn gbajuẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI