Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka ti ẹkun ipinlẹ Kaduna ti sọ pe afurasi ọmọ 'Yahoo' ti ko din ni ogoji lọwọ awọn ti tẹ nipinlẹ Niger.
EFCC sọ pe ijọba ibilẹ Bida ati Minna lọwọ ti tẹ gbogbo wọn, lẹyin iṣẹ iwadii ati ofintoto ti awọn ṣe.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ajọ naa, Dele Oyewale fi sita, o ni iṣẹ iwadii awọn lo fidi rẹ mulẹ pe ogbologbo afurasi alọnilọwọgba lori ayelujara ni gbogbo wọn.
Oyewale fidi rẹ mulẹ pe ọkọ bọgini mẹta, ẹrọ amunawa jẹnẹretọ mẹjọ, ẹrọ amuletutu kan, ẹrọ to n daabobo ohun elo ile, 'stabilizer' meji, ọkada mẹwaa, ẹrọ kọmputa alagbeka mẹjọ, ẹrọ amohundungbẹmu mẹrin ati foonu olowo nla ti ko din ni ọgọta lawọn gba lọwọ gbogbo wọn.
Yatọ si awọn nnkan wọnyi, Oyewale sọ pe oniruuru oogun abẹnugọngọ ti wọn ṣe sinu igba ati awọn nnkan miran bii ọṣẹ agbelẹrọ dudu, kanrinkan, ọti ibilẹ, owo ẹyọ ogun, igbadi, awọtẹlẹ obinrin lawọn tun gba lọwọ wọn.
Bẹẹ lo kadi ọrọ rẹ nilẹ pe gbogbo wọn ni yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.
No comments:
Post a Comment