Lẹyin ipade pẹlu awọn olori ologun, ijọba Kwara fi aadọjọ alupupu ta wọn lọrẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 27, 2025

Lẹyin ipade pẹlu awọn olori ologun, ijọba Kwara fi aadọjọ alupupu ta wọn lọrẹ


Ijọba ipinlẹ Kwara ti fi ọkada alupupu ti ko din ni aadọjọ (150) ta awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ologun lọrẹ, lati le jẹ ki iṣẹ eto aabo tubọ kẹsẹjare.

Awọn okada naa la gbọ pe yoo mu iṣẹ eto aabo ya gidi, nipa igbokegbodo to ja geere, lai si idiwọ.

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pe awọn alupupu naa yoo mu iṣẹ rọrun fun awọn ologun, paapaa lati le dede awọn agbegbe ti oniruuru iwa to le tako eto aabo ti fẹẹ waye.

Atẹjade ti amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode, Kọmureedi Olayinka Fafoluyi fi sita jẹ ko di mimọ pe awọn alupupu ọhun yoo ṣiṣẹ de agbegbe ti ọkọ ko ti le rin bii inu igbo, nibi ti awọn oniṣẹ ibi sapamọ si lati maa fi ṣiṣẹ buruku wọn.

Fafoluyi tọpọ mọ si Solace fidi rẹ mulẹ pe laipẹ yii ni awọn oniṣẹ ibi naa bẹrẹ sii da alaafia ati eto aabo agbegbe Guus ati Ariwa Kwara laamu.

O ni lọjọ Aje, ọsẹ yii, tii ṣe ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2025 ni Gomina AbdulRazaq lewaju ikọ apapọ eleto aabo lọ sijọba ibilẹ Kaiama lati gbogun ti awọn ọdaran.

"Lẹyin wakati mẹrinlelogun, gomina tun ṣepade pẹlu ọgagun agba lorileede yii, Lieutenant General Olufemi Olatubosun Oluyede, nileeṣẹ rẹ to wa ni Ahmadu Bello House, Ilorin," Fafoluyi sọ ninu atẹjade naa.

O sọ pe nibẹ ni gomina ti ṣeleri lati pese awọn irinṣẹ ti yoo mu ki iṣẹ ya, lati gbogun ti awọn ọdaran naa, ki alaafia le jọba niluu.

Bakan naa lo tun fidi rẹ mulẹ pe lati tubọ jẹ ki eto aabo f'ẹsẹ mulẹ daadaa, awọn alakoso ijọba ibilẹ naa ti ra ọkada alupupu to le ni ọọdunrun fawọn Fijilante.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI