Ẹgbẹrun meji arinrin-ajọ lọ silẹ mimọ Hajj gba abẹrẹ ajẹsara ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, May 1, 2025

Ẹgbẹrun meji arinrin-ajọ lọ silẹ mimọ Hajj gba abẹrẹ ajẹsara ni Kwara


Gbogbo awọn arinrin-ajo lọ silẹ mimọ Hajj lati ipinlẹ Kwara ni wọn ti bẹrẹ sii gba abẹrẹ ajẹsara bayii, lati le wa ni ilera pipe, bi wọn ba debẹ.

Ileeṣẹ to n ri sọrọ irin-ajo Hajj nipinlẹ naa, Kwara State Muslim Pilgrims Welfare Board logo fi ikede naa sita, nibi ti wọn ti ṣalaye pe awọn arinrin-ajo to le lẹgbẹrun meji (2,174) kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindilogun nipinlẹ naa ni wọn ti gba abẹrẹ ajẹsara ọhun.

Akọwe agba ileeṣẹ naa, Alaaji Abdulsalam Abdulkadir ninu atẹjade to buwọ lu, fidi rẹ mulẹ pe wọn gba abẹrẹ ọhun ṣaaju ọjọ kẹwaa ti wọn yoo bẹrẹ irin-ajo wọn.

Abẹrẹ ajẹsara yii ni yoo jẹ ki wọn wa ni ilera pipe ni gbogbo asiko ti wọn yoo lo ni Hajj, yoo di daabo bo wọn kuro lọwọ awọn aisan bii oral polio, yellow fever ati influenza.

Bakan naa ni awọn alakoso sọ pe ki ẹnikẹni to ba ṣakiyesi ohunkohun lara tere beere fun amọran lati ọdọ awọn akọṣẹmọṣẹ eleto ilera 

Alaga ileeṣẹ naa, Ọjọgbọn Jimba Moshood rọ gbogbo awọn arinrin-ajo Hajj lọdun yii layi fọwọsowọpọ pẹlu awọn alakoso eleto ilera ati awọn ajọ ti yoo ṣagbatẹru eto ilera ti wọn yoo tọju wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI