Ileeṣẹ to n ri sọrọ awọn ọmọ ilu nilẹ okeere lorileede Naijiria, Nigerians in Diaspora Commission (NiDCOM) ti parọwa sijọba ilẹ Cape Verde lati tu awọn arinrin-ajọ Naijiria mẹfa ti wọn wa lahamọ orileede naa silẹ.
NiDCOM sọ pe irin-ajo afẹ lawọn mẹfẹẹfa ọhun lọ fun nilẹ Cape Verde, ati pe ojulowo ọna ni wọn gba lati lọ, kii ṣe pe wọn fẹ wa tẹdọ sibẹ.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ati alakoso eto iroyin ajọ naa, Abdur-Rahman Balogun fi sita l'Ọjọru, ọsẹ yii, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹrin, o ṣalaye pe orileede Sẹnẹgal ni wọn gba debẹ.
Balogun tẹsiwaju pe isinmi irin ajo afẹ ni awọn eeyan naa n lọ fun, lati gbadun ara wọn, nigba ti wọn fẹsun kan wọn lẹnubode pe wọn ko ni owo to to lati fi wọ orileede naa, to si mu ki wọn gba ẹrọ ibanisọrọ gbogbo wọn silẹ, pẹlu erongba lati ma ṣe jẹ ki wọn ni anfaani lati pe ẹnikẹni fun iranwọ.
Ileeṣẹ NiDCOM sọ pe aarin ọdun mẹẹdogun si mọkanlelọgbọn ni ọjọ ori awọn mẹfẹẹfa ọhun, ti wọn ko si jẹ ki wọn lanfaani si awọn ẹtọ labẹ ofin.
Wọn jẹ ko di mimọ pe ọkan lara awọn arinrin-ajo afẹ ọhun lo n lo oogun fun itọju ailera rẹ, ti wọn ko si jẹ ko ni anfaani si oogun naa lati fi tọju ara rẹ.
“A n rawọ ẹbẹ si awọn alakoso ileeṣẹ aṣọbode ilẹ Cape Verde lati dakun tọju awọn arinrin ajo pẹlu ọwọ, ki wọn si fi wọn si ọkọ baluu to wa nitosi lati le pada si Dakar, nibi ti wọn yoo ti dari pada si Naijiria,” atẹjade ọhun lo sọ bẹẹ.
David James Udoh, Lily Dada, Oghenero Adaware, Sherifat Abimbola Ogundairo ati Jesutomi Aina ni wọn pe orukọ awọn eeyan naa.
A gbọ pe ileeṣẹ kan to n ṣagbatẹru eto irin ajo afẹ ti wọn pe ni 'Ìrìn Travels', lawọn eeyan naa ba lọ.
No comments:
Post a Comment