Ijọba Kwara ti opopona Ibrahim Taiwo pa, lati da ọda Asphalt - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, April 23, 2025

Ijọba Kwara ti opopona Ibrahim Taiwo pa, lati da ọda Asphalt


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gbe opopona Ibrahim Taiwo ti atunṣe n lọ lọwọ nibẹ pa.

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii la mu iroyin naa wa fun un yin pe opopona ọhun ti de ipele karundinlọgọrun lati pari, ki awọn araalu si le maa jẹ igbadun opopona to ja geere.

Ni bayii, ijọba ti kede pe ohun ti ti opopona ọhun pa, bẹrẹ lati oni, Ọjọru, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kerin.

Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna feto iṣẹ ode, Ọnarebu Abdulquawiy Olododo fi sita, o ni wọn yoo bẹrẹ sii da ọda to ipari ti a mọ si Asphalt sopopona naa, ko le dun un gba daadaa.

Olododo sọ pe awọn ọkọ yoo gba ọna miran bii Wahab Folawiyo to wa ni opopona Unitu ati Objo.

O gba awọn araalu lamọran lati fara da asiko ti wọn yoo fi ti opopona ọhun pa, ki wọn si dẹkun ere sisa, lati le dẹkun ijamba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI