O ṣẹlẹ! Oniṣẹ ina gan mọna l'Ọyọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 25, 2025

O ṣẹlẹ! Oniṣẹ ina gan mọna l'Ọyọ


Kayeefi lọrọ iku gendekunrin, ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan ti wọn lo gan mọna niluu Eruwa, ijọba ibilẹ Ibarapa, ipinlẹ Oyo.
 
Ọjọru, ọsẹ yii ni gendekunrin naa gan mọna lagbegbe Odi Babaode niluu Eruwa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Ọgba agba ileeṣẹ panapana nipinlẹ naa, Yemi Akinyinka to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe ori opo ina ijọba ti wọn pe ni 33kva ni ọkunrin naa gan mọ.
 
Akinyinka sọ pe ọkunrin oniṣẹ ina naa fẹẹ ṣe atunṣe lori ina to bajẹ, lo ti pade iku ojiji.
 
O sọ pe ọkunrin naa to yan iṣẹ ina (electrician) ko duro ki wọn pa ina mọnamọna lasiko naa, to fi gun ori opo, nibi to gba dero ọrun alakeji.
 
Ọga agba naa sọ pe deedee agogo mẹta kọja iṣẹji mọkandinlọgbọn ni wọn ranṣẹ pe awọn lori iṣẹlẹ naa, ko to di pe awọn gbera lọ sibẹ.
 
O wa gba awọn eeyan lamọran lati ṣọra nipa bi wọn yoo ṣe maa gun opo ina, ati pe wọn gbọdọ maa kọ iṣẹmọṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI