Oluṣiro eto iṣuna tuntun ni Kwara ṣepade pẹlu awọn alẹnulọrọ, o loun ko fẹ k'ẹnikẹni lẹbọ-lẹru - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 27, 2025

Oluṣiro eto iṣuna tuntun ni Kwara ṣepade pẹlu awọn alẹnulọrọ, o loun ko fẹ k'ẹnikẹni lẹbọ-lẹru


Lojuna lati di gbogbo kọlọfin lẹta eto iṣuna, ati owo ijoba, alabojuto eto iṣiri owo tuntun, Fatai Olajide ti ṣepade papọ pẹlu awọn ileeṣẹ ijọba nipinlẹ Kwara.

Olajide ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq bura fun lọsẹ to kọja yii gẹgẹ bi alabojuto agba fun eto iṣiro owo ijọba Kwara.

Lẹyin ibura naa, pẹlu erongba lati jẹ ki iṣẹ rọrun fun un, ati lati ni ibaṣepọ to dan mọnran pẹlu awọn ileeṣẹ tọrọ owo kan, ni alakoso agba naa fi ranṣẹ pe awọn ọga agba ati alẹnulọrọ loriṣiriṣi ẹka ileeṣẹ ijọba sibi ipade to gbe kalẹ.

Ọkunrin naa loun fẹ ki gbogbo nnkan han sita lai fi ohunkohun pamọ nipa bi owo ṣe n wọle, ati bi owo ṣe n jade nipinlẹ naa.

Lara awọn to wa nibi ipade ọhun ni awọn agbaagba nileeṣẹ akọwe ijọba, ti Ọjọgbọn Mamman Saba Jibril jẹ adari re; Kọmiṣanna feto iṣuna, Ọmọwe Hauwa Nuru; Oluṣiro owo agba, Alaaji Abdulganiyu Sani; akọwe agba lẹka eto igbe aye irọrun ti ileeṣẹ olori awọn oṣiṣẹ ijọba, Arabinrin Mercy Shittu; to fi mọ nileeṣẹ to n ri sọrọ awọn oṣiṣẹ, Alaaja Jimoh Kafayat.

Olajide sọ pe ohun ti ijọba n fẹ ni lati jẹ ki eto ipawowọle ati nina owo ijọba han si araalu, ati lati le ko ara ẹni nijanu.

Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe ṣiṣe akoso eto owo ijọba lọna ati ilana to dara, jẹ ọkan pataki lara awọn ọna to n mu ki ijọba rere tẹsiwaju.

O wa beere fun ifọwọsowọpọ awọn alẹnulọrọ naa, lati le jẹ ki iṣẹ rọrun fun gbogbo wọn pata, lai fi ohunkohun pamọ funra wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI