Ileeṣẹ to n ri sọrọ okoowo, agbekalẹ igbalode ati imọ-ẹrọ nipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn n ko ipa ribiribi ninu ayipada eto ọrọ aje kaakiri ipinlẹ naa, nipa agbekale, okoowo ati idagbasoke iṣẹ akanṣe laaarin ilu.
Kọmiṣanna, Ọnarebu Damilola Yusuf Adelodun, lo sọ eyi di mimọ l'Ọjọru, oni lasiko to n ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa aṣeyọri ileeṣẹ naa lori awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to n lọ lọwọ kaakiri ipinlẹ Kwara fawọn akọroyin.
Eto ọhun to waye ninu gbọngan ipade ileeṣẹ to n ri sọrọ iṣuna niluu Ilorin.
Ọnarebu Damilola jẹ ko di mimọ pe ileeṣẹ naa n ṣakoso awọn akanṣe iṣẹ nla-nla mẹwaa ọtọọtọ kaakiri aarin gbungbun ipinlẹ naa, leyi ti mẹrin ti pari, ti mẹfa si n lọ lọwọ.
O ni akitiyan ti ileeṣẹ naa n ṣe, lo lọ nibamu pẹlu afojusun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, ẹni to farajin fun idagbasoke okoowo, agbekalẹ igbalode ati anfaani okoowo fun gbogbo araalu.
Lara awọn akanṣe iṣẹ naa ni Ilorin Innovation Hub, Gasoline-to-Electric Vehicle Conversion Project, ti ṣagbekalẹ rẹ ni ajọṣepọ pẹlu fasiti Kwara to wa ni Malete, Kwara Garment Factory, ati Sugar Film Factory.
No comments:
Post a Comment