Araalu to ba fẹẹ jẹ anfaani KWASSIP lo gbọdọ ni nọmba idanimọ ọmọ ilu - Ijọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 21, 2025

Araalu to ba fẹẹ jẹ anfaani KWASSIP lo gbọdọ ni nọmba idanimọ ọmọ ilu - Ijọba Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti kan an nipa fun gbogbo awọn araalu ti wọn fẹẹ jẹ anfaani ipinlẹ naa labẹ ileeṣẹ KWASSIP, ni lati gba nọmba idanimọ ọmọ ilu ti a mọ si KWASRRA.

KWASSIP ni wọn pe ni Kwara State Social Investment Programme lo n ṣagbatẹru eto anfaani iranlọwọ fawọn araalu.

Ninu atẹjade ti alakoso agba ileeṣẹ KWASSIP, Ọmọwe Abdulwasiu Olayinka Tejidini fi sita loni, Ọjọru, Wẹside, o ni dandan ni fun araalu to ba fẹẹ jẹ anfaani ileeṣẹ naa lati ni nọmba idanimọ KWASRRA.

Tejidini ṣalaye pe eyi ni yoo jẹ ki awọn ni ẹkunrẹrẹ akọsilẹ orukọ araalu to ti jẹ anfaani eto ijọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI