Kwara United yoo gbe ife ẹyẹ Gateway Games - Balogun ikọ naa ṣeleri fun Gomina AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 26, 2025

Kwara United yoo gbe ife ẹyẹ Gateway Games - Balogun ikọ naa ṣeleri fun Gomina AbdulRazaq


Awọn agbabọọlu Kwara ti f'ọkan Gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq balẹ wi pe awọn yoo gba ife ẹyẹ wale ninu idije ife ẹyẹ apapọ to n lọ lọwọ nipinlẹ Ogun, iyẹn Gateway Games.

Awọn agbabọọlu naa ni wọn ti yege si ipele aṣekagba ti a mọ si Final bayii.

Balogun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu naa, Dennis Sunday gave sọrọ idaniloju yii lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ lẹyin ti wọn bori pẹlu aamo ayo kan si odo, nibi ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu awọn akẹgbẹ wọn lati Kaduna.

Sunday sọ pe oun to da wọn loju ni pe awọn yoo gbe ife ẹyẹ ọhun lati le fi idaniloju akitiyan gomina lori eto ere idaraya nipinlẹ naa.

Kwara yoo koju awọn akẹgbẹ wọn lati ipinlẹ Ogun ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun ni papa iṣere MKO Abiọla laago mẹfa irọlẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI