Lojuna lati mu imugbooro ba iṣẹ agbẹ, paapaa awọn ohun ọsin, ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣagbekalẹ eto lẹka iṣẹ ọwọ ati okoowo ti a mọ si Entrepreneur, eyi ti yoo maa ri sọrọ awọn ohun ọsin.
Eto yii ni iroyin fi to wa yoo ṣe iranwọ fawọn ọdọ, paapaa awọn agunbanirọ ti wọn n sin ilẹ baba wọn.
Kọmiṣanna f'ọrọ ohun ọsin nipinlẹ naa, Arabinrin Oloruntoyosi Thomas lo sọrọ naa laipẹ yii lasiko to ṣe abẹwo si ọgba awọn agunbanirọ to wa lagbegbe Yikpata, ẹkun Tsaragi, nijọba ibilẹ Edu.
Kọmiṣanna naa ti akọwe agba ileeṣẹ naa, Alaaji Yahaya Mohammed kọwọrin pẹlu rẹ ṣalaye pe lara awọn erongba ijọba ipinlẹ naa ni lati sọ ipinlẹ ọhun di agbegbe ti igbelarugẹ yoo ti ba idagbasoke ohun ọsin, ati okoowo awọn ọdọ.
Siwaju sii lo ni ileeṣẹ naa n ṣeto lori ibaṣepọ laarin awọn ati ileeṣẹ agunbanirọ to wa ni Yikpata gẹgẹ bi ibi idanilẹkọọ fun awọn agunbanirọ ati awọn ọdọ miran ti wọn nifẹ si iṣẹ ohun ọsin.
No comments:
Post a Comment