Awọn araalu yoo gba iwe aṣẹ CofO laipẹ ni Kwara - Alakoso agba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, May 16, 2025

Awọn araalu yoo gba iwe aṣẹ CofO laipẹ ni Kwara - Alakoso agba


Igbesẹ lo ti bẹrẹ bayii fun ipinlẹ Kwara lati fun awọn araalu niwe aṣẹ lori ilẹ ati dukia wọn, eyi ti wọn n pe ni Certificate of Occupancy (CofO).

Awọn ti ko din ni 354 la gbọ pe wọn ileeṣẹ to n ri sọrọ ayẹwo ilẹ, Kwara State Geographic Information Service (KWGIS) fẹẹ fi ontẹ lu.

Nigba to n fidi rẹ mulẹ, alakoso agba fun ileeṣẹ naa, Abdulkareem Babatunde Sulyman sọ pe igbesẹ ti n lọ lati ṣayẹwo gbogbo awọn ilẹ ti wọn gbe wa, lati mọ boya ojulowo ni wọn.

Bakan naa lo tun ni lẹyin ayewo ni wọn yoo too gba iwe aṣẹ CofO, ni saa akọkọ ọdun 2025.

Sulyman sọrọ naa lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ nibi ipade oniroyin to pe nileeṣẹ to n ri sọrọ eto iroyin niluu Ilorin.

O ṣalaye pe ilẹ to to 354 lawọn ti n ṣagbeyẹwo wọn lọwọ ti a mọ si "Charting for Confirmation", nigba ti awọn kan ti de ipele 247 lati gba iwe aṣẹ emi ni mo ni ilẹ, CofO.

O ni awọn n duro de ki Gomina buwọ luu, ki wọn too pin in sita.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI