Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ meji gbako ni idije naa yoo fi waye, iyẹn lọjọ Ẹti ati ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ẹgbẹrun lọna igba naira ni ẹni to ba gbe ipo akọkọ yoo gba, nigba ti onipo keji yoo gba ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira, nigba ti onipo keji yoo gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira.
Idije ere ayo ọlọpaa ọhun ti ileeṣẹ Seaman Schnapps ṣagbatẹru rẹ ni yoo waye niwaju aafin Orile Ilawọ ni wọn yoo ṣe laaarin agogo mẹsan si mẹwaa owurọ.
Aṣọ adirẹ lawọn akopa to ti forukọ silẹ yoo wọ lati fi kopa ninu idije naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Nigba to n gbe iroyin naa si awọn akọroyin leti niluu Abẹokuta, ọlọwọ-ọtun Kabiyesi, Ọgbẹni Atanda Ọlọkọ jẹ ko di mimọ pe kii ṣe igba akọkọ ree ti idije ọhun yoo maa waye, ṣugbọn to ni ọna ara ni tọdun yii gba yọ, pẹlu bo ṣe wọnu idije ere apapọ Naijiria, iyẹn Gateway Games 2024.
Ọlọkọ sọ siwaju pe yatọ si ẹbun owo tawọn to ba gbegba oroke yoo gba, gbogbo awọn akopa patapata ni yoo gba oniruuru ẹbun, ti wọn yoo si tun da wọn laraya, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe lọdọọdun.
No comments:
Post a Comment