Ẹgbẹ awọn Imaamu ati Aafa nipinlẹ Ogun ti ṣe ikilọ nla fawọn ẹlẹsin musulumi lọ si silẹ Saudi Arabia fun irin ajo ile mimọ Hajj tọdun 2025.
Wọn lawọn ko fẹ ki wọn lọ silẹ mimọ lati lọ maa huwa ti yoo doju ogo ipinlẹ Ogun bolẹ, bi ko ṣe pe ki wọn ṣe awọn ohun ti yoo pokiki ogo ipinlẹ naa.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita lọjọ Aje, ọsẹ yii, eyi ti akọwe agba, Alaaji Tajudeed Adewunmi ati Aarẹ ẹgbẹ naa, Shakyh Sikirullahi Babalọla buwọ lu, wọn sọ pe ilẹ mimọ ni Hajj jẹ, kii ṣe ibi ti eeyan ti n ṣe awọn ohun to lodi si ofin.
“Irin ajo Hajj jẹ ibi ilẹ mimọ to gba iwa mimọ ati ifọkansin, iwa ọmọluabi ati fifi ara jin fun Allah,” atẹjade naa sọ bẹẹ.
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lori atẹjade naa niluu Abẹokuta, Shaykh Babalọla rọ awọn to lọ fun irin ajo ilẹ mimọ Hajj naa lati tẹle ofin ati ilana ilẹ naa gẹgẹ bii musulumi.
“Iwa aigbọran tabi aitẹle ilana lẹ dabaru irin ajo Hajj eeyan ati awọn yooku,” o ṣekilọ.
Agba ẹlẹsin naa sọ pe ohun to ṣe pataki ni lati maa tẹle gbogbo ilana ati alakalẹ awọn alaṣẹ ati alakoso, leyi to lo wa lara ojuṣe musulumi ti Kuraani fidi rẹ mulẹ.
Agba ẹlẹsin naa sọ pe ohun to ṣe pataki ni lati maa tẹle gbogbo ilana ati alakalẹ awọn alaṣẹ ati alakoso, leyi to lo wa lara ojuṣe musulumi ti Kuraani fidi rẹ mulẹ.
Bakan naa lo sọ pe ki gbogbo wọn maa ṣe iranwọ funra wọn bi awọn arugbọ, awọn to n ṣaisan, gẹgẹ bi Kuraani ṣe laa kalẹ.
“Ẹ ma ṣe fi ara yin jin fun oniruuru ohun ti yoo gbe ọkan yin kuro ninu nnkan ti ẹ lọ ṣe nibẹ bii apọju aworan yiya tabi ohun ti yoo mu ki ọwọ yin dilẹ. Ẹ jẹ ki gbogbo igba ati asiko yin maa kun fun iranti Allah, ati kika Kuraani,” o sọ bẹẹ.

Ni afikun, ipele akọkọ awọn to lọ silẹ mimọ Hajj lati ipinlẹ Ogun ni iroyin fi to wa leti pe wọn ti de si Hajj, ni papakọ ofurufu Ọmọọba Mohammad Bin Abdulaziz to wa ni Madinah.
Deedee agogo kan oru ku iṣẹju mẹẹdogun la gbọ pe wọn balẹ si papakọ ofurufu naa lọjọ Aje, ana.
Irọlẹ ọjọ Aiku ni wọn gbera lati papakọ ofurufu Muritala Muhammed to wa l'Ekoo.
Irọlẹ ọjọ Aiku ni wọn gbera lati papakọ ofurufu Muritala Muhammed to wa l'Ekoo.
No comments:
Post a Comment