Ile-ẹjọ giga apapọ to wa lagbegbe Ikoyi nipinlẹ Eko ti ju ọrẹ meji kan, Babatunde Peter Ọlaitan ati Tobilọba Ọlamide sẹwọn oṣu mẹfa pẹlu iṣẹ aṣekara.
Onidajọ Alexander Owoẹyẹ lo gbe idajọ naa kalẹ l'Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ to kọja, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ ti a mọ si EFCC lo fẹsun titẹ owo naira to jẹ aami idanimọ ilẹ Naijiria loju mọlẹ.
Ninu atẹjade ti ajọ naa fi soju opo wọn lọsan ọjọ Aje ana, wọn ṣalaye pe niṣe lawọn mejeeji naa n na owo ọhun lọna ti ko ba ofin mu, ti wọn si gba pe lotitọ lawọn jẹbi.
EFCC sọ pe ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2025 ni Ọlaitan ati Ọlamide n na owo naira to jẹ igba naira lode faaji alẹ to waye loju ọna Macdonald to wa lagbegbe Ikoyi, ipinlẹ Eko.
Bi awọn mejeeji ṣe n jo loju agbo naa, ni wọn tun n tẹ owo naira mọlẹ, ẹsun ti wọn lo tako iwe abala kọkanlelogun, ipin kinni ninu iwe ofin owo naira ti CBN ṣe lọdun 2007.
Ori ikanni ayelujara ti TikTok la gbọ pe aṣiri awọn mejeeji yii ti tu, ninu fọnran ti wọn gbe sibẹ, eyi to tẹ ajọ EFCC lọwọ lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ti wọn si ṣewadi wọn.
Loju ẹsẹ ni EFCC ti fiwe pe awọn mejeeji lati yọju, ki wọn si wa sọ tẹnu wọn lori iwa ti wọn wu naa.
Ọjọ karun-un, oṣu yii ni EFCC sọ pe awọn mejeeji yọju, ti wọn si ṣalaye tẹnu wọn lori ohun to ṣẹlẹ, eyi to mu ki ajọ naa foju wọn ba ile-ẹjọ.
Onidajọ Owoẹyẹ, nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ sọ pe awọn ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ kọja nnkan ti wọn le dawọ bo mọlẹ, to si paṣẹ pe ki wọn lọ fi ẹwọn oṣu mẹfa-mẹfa gbara.
Bakan naa ni Onidajọ naa faaye owo itanran ẹgbẹrun lọna igba naira wilẹ fẹni kọọkan, iyẹn bi wọn ko ba fẹẹ lọ sẹwọn lori ẹsun naa.
No comments:
Post a Comment