Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn ara agbegbe Iyana Era to wa loju ọna Tradefair si Agbara nipinlẹ Ekoo lọjọ Aje to kọja yii nigba ti ọkọ ayọkẹlẹ Lexus kan lọ ko sabẹ tirela.
Eeyan kan ni iroyin fi to wa leti pe o jade laye loju ẹsẹ nibi ijamba naa, t'awọn meji si farapa kọja sisọ.
Ninu atẹjade ti alakoso ajọ ẹṣọ aabo oju popona tijọba apapọ, iyẹn FRSC, ẹkun tipinlẹ Ekoo, Ọgbẹni Kẹhinde Hamzat fi sita, o ni nnkan bi agogo mẹfa ku iṣẹju mẹrinlelogun aarọ ni ijamba ọhun waye.
Ikorita ibudokọ Iyana Ẹra lo sọ pe ọkọ ayọkẹlẹ Lexus alawọ eeru ti nọmba idanimọ rẹ jẹ LSR 545 JN lo lọ kọlu tirela Mack ti nọmba idanimọ rẹ jẹ AKD 579 XM.
Hamzat ṣalaye pe ere asapajude ti awakọ ayọkẹlẹ naa n ba lọ, lo ṣokunfa ijamba ọhun, nigba ti ijanu rẹ ja lori ere
O ni awọn marun latowo fara kaaṣa ninu ijamba ọhun, to si lori ko awọn mẹrin yọ, bo tilẹ jẹ awọn meji ko farapa.
Siwaju sii lo sọ kani awakọ ayọkẹlẹ naa ko sare asapajude naa, o ṣee ṣe ki ẹmi eeyan ma ṣe ba a lọ.
O loju ẹsẹ t'awọn debẹ ni wọn ti tete gbe awọn tp farapa lọ si ile iwosan jẹnẹra ti Alimọṣọ nipinlẹ Ekoo fun itọju.
Lafikun, o rọ awọn awakọ lati dẹkun ere asapajude, nitori pe ijamba lo maa n da silẹ, to si le mu ẹmi lọ.
No comments:
Post a Comment