Ifarasiṣẹ awọn oṣiṣẹ lo n mu wa tẹsiwaju ni Kwara - Gomina AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, May 1, 2025

Ifarasiṣẹ awọn oṣiṣẹ lo n mu wa tẹsiwaju ni Kwara - Gomina AbdulRazaq


"Ni ayẹyẹ ọjọ awọn oṣiṣẹ lagbaye ti ọdun 2025, Mo fi tọwọtọwọ ki gbogbo ọkunrin ati obinrin lẹka iṣẹ ijọba ati aladani, eyi ti igbiyanju wọn ti jẹ ohun amuṣagbara fun eto ọrọ aje wa ati ọjọ iwaju agbegbe wa," wọnyi lohun ti Gomina AbdulRazaq fi bẹrẹ ọrọ rẹ ni ayajọ ọjọ awọn oṣiṣẹ lagbaye lonii.

"Fun awa nipinlẹ Kwara, a dupẹ gidigidi fun ipa ti awọn oṣiṣẹ n ko - yala gẹgẹ bi oṣiṣẹ ijọba, agbẹ, oṣiṣẹ ileeṣẹ, olukọ, eleto ilera, onimọ-ẹrọ, oniṣẹ ọwọ, ati awọn akọṣẹmọṣẹ kaakiri ẹka iṣẹ. Ifarajin ati ọkan akikanju wọn fun iṣẹ ati ẹkọ wọn lo jẹ ipo si idagbasoke ati ilọsiwaju wa."

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq wa ṣeleri wi pe ifarajin iṣakoso oun lati gbe Kwara larugẹ nibi ti awọn oṣiṣẹ yoo ti ṣiṣẹ, nibi ti idasilẹ okoowo yoo ti diee, nibi ti imọ yoo ti di lilo, ati nibi ti awọn ẹka ileeṣẹ yoo ti máa ṣe rere.

Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe ipinnu awọn ni lati ṣagbekalẹ eto ti yoo ro awọn oṣiṣẹ lagbara, mu idagbasoke ba eto ọrọ aje, ati lati fa oju awọn olokoowo mọra.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI