Beeyan ba gun ẹṣin ninu awọn araalu Abẹokuta, paapaa awọn to wa lẹkun Guusu idibo Abẹokuta [Abẹokuta South Federal Constistuency] lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii, ẹni naa ko nii kọsẹ rara.
Tilu tijo ati ayọ lawọn araalu Abẹokuta fi tẹwọ gba eto ironilagbara ti Ọnarebu to n ṣoju wọn nile igbimọ aṣofin kekere niluu Abuja, Ọnarebu Afọlabi Afuapẹ ṣagbekalẹ rẹ fun wọn.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, owo ti ko din ni miliọnu marundinlaadọrin [N65,000,000] naira ni ẹnikọọkan gba lati fi bẹrẹ okoowo, leyi ti yoo mu eto ọrọ aje wọn ni ilọsiwaju.
Yatọ si pe awọn eeyan gba owo, ọpọ awọn to kọ iṣẹ ọwọ ni wọn tun gba irinṣẹ to tọ si wọn lọjọ naa.
Gbagede ayẹyẹ ti aafin Alake ilẹ Ẹgba to wa ni Ake niluu Abẹokuta ni eto ọhun ti waye, nibi ti awọn ti ko din ni ẹgbẹrun meji ti peju.
Lara awọn ohun ti gbajumọ oloṣelu naa pin fawọn araalu ni Kẹkẹ Maruwa, Ọkada alupupu, Ẹrọ ijata, Maṣiini iranṣọ, Ẹrọ amohuntutu [Freezer], Apo awọn eleto ilera [First Aid Box], to fi mọ Kẹkẹ awọn alaabọ ara.
Nigba to n sọrọ, Ọnarebu Afuapẹ jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ ojuṣe awọn ni lati ṣoju-ṣofin, sibẹ, iyẹn ko sọ pe kawọn ma ṣe ṣe iranwọ fawọn araalu, paapaa awọn to ku diẹ kaato fun.
''A ni lati maa ṣe iranwọ fawọn eeyan wa ti wọn nilo iranlọwọ, a ni lati lo ipo wa lọna to tọ. Lotitọ, niṣe la n ṣoju ṣofin, gẹgẹ bi iṣẹ ti a gba, sibẹ, a ni lati ro awọn eeyan lagbara, ki eto ọrọ aje wa le tubọ gbooro sii.
''Kii ṣe ka ṣoju-ṣofin nikan, a tun nilo lati ṣokunfa bi iṣẹ akanṣe yoo ṣe wa laarin ilu. Ohun ti mo n ṣe yii ni awọn eeyan n reti lati ọdọ mi. Igba ti a n polongo ibo, lawọn eeyan ti beere fun un lọwọ wa, ti a si ṣeleri fun wọn.''
No comments:
Post a Comment