Awọn arinrin ajo Hajj jabọ fun Gomina AbdulRazaq ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 5, 2025

Awọn arinrin ajo Hajj jabọ fun Gomina AbdulRazaq ni Kwara


"Lonii, mo gbọ abọ ti Amiru (Ameerul) Hajj ati to jẹ Olupo tiluu Ajaṣẹ-Ipo, Ọba Ismail Yahya Alebioṣu jẹ fun mi nipa bi awọn arinrin-ajo Hajj ṣe n ṣe si, ṣaaju ọjọ lati gun oke Arafa l'Ọjọbọ," Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo sọ eyi l'Ọjọru ana.

Gomina AbdulRazaq dupẹ lọwọ Ọba alaye naa, Ọba Alebioṣu lori idari rẹ ati ọkan akikanju pẹlu ifarajin to fi lewaju awọn to lọ ṣoju ipinlẹ naa.

Nibi ijabọ naa ni wọn ti lo anfaani rẹ lati gbadura fun ilẹ Naijiria lapapọ, to fi mọ ipinlẹ Kwara.

Bakan naa ni Gomina tun sọ pe oun ṣabẹwo si ikọ to n mojuto ọrọ ounjẹ awọn arinrin-ajo naa, lati rii daju pe wọn n tọju wọn bo ti yẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI