Akẹkọọ UNILAG dawati l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 6, 2025

Akẹkọọ UNILAG dawati l'Ekoo


Awọn mọlẹbi gendekunrin, ẹni ọdun mọkanlelogun kan, James Ayọdọla Oluṣọla ti rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ Naijiria lati ba wọn wa ọmọ naa to dawati.

Ọkan lara awọn akẹkọọ fasiti tipinlẹ Eko ti a mọ si UNILAG ni Oluṣọla, ẹni ti wọn lo dawati lati ọjọ kẹsan, oṣu karun-un, ọdun 2025.

Joy Oluṣọla to jẹ ẹgbọn James to pariwo sita jẹ ko di mimọ pe ipele kẹrin [400level] ni James wa ni fasiti naa titi digba to fi poora.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni niṣe ni James dagbere wi pe oun fẹẹ de Idumọta, to si wọ mọto lọ. Alọ ni wọn ri, ko sẹni to ri apadabọ James titi di asiko yii.

‘Gbogbo akitiyan lati ṣe, to si jẹ pe pabo lo ja si. O ti pe ọjọ mẹrinlelogun bayii ti a ti n wa a. Ibanujẹ lo n jẹ wi pe a ko tii gburo rẹ sibikibi titi di asiko yii.

''Awọn ọlọpaa ko yara si bi a ṣe n wa aburo mi, a ko mọ ohun to n la kọja lọwọ, inu wa yoo si dun bi a ba ri ẹnikẹni lati ran wa lọwọ,'' Joy ṣalaye.

Joy sọ pe ẹnikẹni to ba gburo aburo oun, ki wọn pe Jerry Oluṣọla sori ẹrọ ibanisọrọ 08105980316, tabi Nelson sori 09159855961 tabi ki wọn fi to ileeṣẹ ọlọpaa to ba wa lagbegbe wọn leti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI