Ko si ede to ga ju ede Yoruba lọ lagbaye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 7, 2025

Ko si ede to ga ju ede Yoruba lọ lagbaye

Ajọ to n ṣagbatẹru didaabo bo aṣa ati ajogunba ilẹ Yoruba, Foundation for the Preservation of Yoruba Culture and Heritage ti sọ ọ di mimọ pe ko si ede tabi aṣa to ga ju ede ati aṣa Yoruba lọ lagbaye.

Ajọ naa sọ pe bi awọn ede ati aṣa ṣe ṣe pataki si oniruuru ẹya to wa lagbaye, naa lo ṣe pataki si awọn ọmọ Yoruba.

Ọrọ yii lo jẹyọ nibi akanṣe eto ọlọdọọdun ti ajọ naa gbe kalẹ niluu Abẹokuta tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun.

Gbọngan aṣa ti a mọ si June 12 Cultural Centre to wa ni Kutọ niluu Abẹokuta ni eto naa ti wọn pe akori rẹ ni 'Yoruba Ti Goke Agba' ti waye lọjọ Iṣẹgun Tusidee to kọja yii.

Eto ọhun ni ogbontarigi agbaṣaga Oloye Yẹmi Ẹlẹbuibọn, ẹni ti Ọgbẹni Ogundeji Ẹlẹbuibọn jẹ alaga rẹ, ti agba olukọ ede Yoruba ni Naijiria, Ọmọwe Adesọji Aderẹmi Fajẹnyọ ti jẹ oludanilẹkọọ agba.

Lara awọn to tun wa nibi akanṣe eto naa ni Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ ti Amọna Baaroyin ilu Ẹgba, Oloye Tajudeen Ọladẹinde ṣoju fun; Olowu tiluu Owu, Ọba Ọjọgbọn Saka Adelọla  Matẹmilọla ati awọn ọba ilẹ Benin.

Awọn olujiroro ni akọwe agba tẹlẹ nileeṣẹ to n ri sọrọ aṣa ati irin ajo afẹ nipinlẹ Ogun, Arabinrin Yemi Olanrewaju; oludasilẹ ileeṣẹ Asani and Aduke Foundation, Ọmọwe Arabinrin Ronke Adeboyejo; alakoso agba nileeṣẹ redio Fresh FM l'Abẹokuta, Alagba Goke Babalola ati Alaaji Babatunde Adebayo to jẹ akọwe agba nileeṣẹ to n ri sọrọ ọmọ Naijiria nile okeere to wa lorileede olominira Benin.

Nibi ijiroro naa ni awọn agbaagba ati alẹnulọrọ ninu ede ati aṣa ati iṣẹṣe Yoruba ti fẹnuko lori awọn koko pataki ti ko nii jẹ ede Yoruba lọ soko iparun.

Ọna to dara julọ lati daabo bo ede Yoruba lati ma ṣe jẹ ko parun ni lati maa sọ Yoruba si awọn ọmọ wa nile. A n rọ awọn obi lati bẹrẹ sii so ede Yoruba si awọn ọmọ wọn lati ile.

Ijokoo naa gbe oṣuba kare fawọn alakoso eto ọhun nipa ṣiṣoju Yoruba daradara nipa agbekalẹ eto naa, paapaa nipa aṣọ wiwọ ati lilo ede lasiko ti wọn n ṣe ijiroro, ti wọn si bu ẹnu atẹ lu awọn ti wọn lawọn n gbe eto Yoruba larugẹ, ṣugbọn to jẹ pe adamọdi ede miran ni wọn yoo maa fi sọrọ.

Wọn ni ojuṣe gbogbo ọmọ Yoruba ni lati rii pe ede Yoruba ko lọ soko iparun bo ti wu ko ri.

Wọn ni awọn eeyan alawọ dudu ko gbọdọ maa fi oju tẹmbẹlu ara wọn leyi to maa n jẹ ki wọn kọ ede ati aṣa wọn silẹ nigba miran, ti wọn si ni ko si ede tabi ẹya to ju ede tabi ẹya miran lọ.

Wọn ni awọn iran Yoruba ti dagba debi wi pe wọn ti ni ọgbọn ati oye to pọ, ati pe awọn Yoruba wa lara awọn to ni imọ julọ lagbaye, pẹlu bo ṣe jẹ pe iṣakoso ti ẹya Yoruba ba ṣe, wọn maa n ṣe e daradara nipa iwa ọmọluwabi.

Wọn ni Yoruba lo n lewaju ni gbogbo ẹka lagbaye bii agbẹjọro akọkọ, dokita akọkọ, obinrin akọkọ yi yoo wa ọkọ, ọba akọkọ ti yoo kawe, alawọ dudu akọkọ ti yoo gba aami ẹyẹ iwe litireṣọ kikọ, iwe iroyin akọkọ ti wọn da silẹ ni Naijiria lọdun 1859, ati fasiti akọkọ ti wọn pe ni University College, to fi mọ ẹka oṣelu, Yoruba lo n lewaju.

Ajọ naa ṣakiyesi pe ipenija iṣọkan ati aini ifọwọsowọpọ to dara jẹ ọkan pataki lara awọn ohun to n fa ọwọ aago ede Yoruba ati ilọsiwaju aṣa iran Yoruba sẹyin.

Wọn ni aikii sọ ede Yoruba s'awọn ọmọ ati iwa aikii sọ awọn omo ni orukọ Yoruba tun wa lara pataki iṣoro ti Yoruba n koju.

Nibe ni wọn ti pe fun lilo ede Yoruba lati maa fi kẹkọọ lati le de ibi to ga ninu imọ ẹrọ tẹkinọlọji, gẹgẹ bi wọn ti n ṣe n gun oke agba lawọn orileede bii China, India ati awọn miran.

Siwaju sii ni wọn sọ pe ọna yiyan ọba alaye nilẹ Yoruba ti di idakuda, ti wọn si n pe fun atunto ati atunṣe lori eyi.

Wọn wa pe ijọba ipinlẹ Ogun lati buwọ lu lilo ede Yoruba lati maa fi kọ awọn ẹkọ iṣẹ miran, ki wọn si sọ ede Yoruba di dandan lawọn ile ẹkọ giga, nigba ti wọn tun rọ ile igbimọ aṣofin lati maa lo ede Yoruba fi sọrọ nibi ijokoo wọn.

Wọn pe fun iṣọkan laaarin ẹya Yoruba lati di alafo to wa laaarin awọn adojukọ ti wọn ti la kalẹ yii, ati pe ki gbogbo ọmọ Yoruba lapapọ mọ riri ati pataki ede ati aṣa wọn.

Bakan naa ni wọn sọ pe ki ijọba mu ọrọ didaabo bo ede ati aṣa Yoruba lọkukudu , pẹlu bi wọn ṣe ni awọn eeyan ko ṣiṣẹ nipa didaabo bo aṣa ati ede wọn, nirori pe ko sẹni ti yoo wa lati ita wa a ṣe e fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI