Ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin marun-un ti wọn ko niṣẹ meji ju tita egboogi oloro lọ.
Ọga agba pata fun ileeṣẹ Amọtẹkun, Isaac Ọmọyẹle lo fidi iroyin naa mulẹ lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii niluu Oṣogbo.
Ọmọyẹle ṣalaye pe yatọ si awọn tọwọ tẹ lori ẹsun igbo tita, o ni owo tun tẹ awọn miran lori ẹsun idigunjale.
Makanjuọla Sọdiq, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn; Jide Ojo, ọmọ ọdun marundinlọgbọn; Toheeb Mọruf, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn; Azeez Abdulai, ọmọ ogun ọdun; ati Ademọla Kẹhinde, ẹni ọdun marundinlọgbọn.
Ọmọyẹle nigba to n sọrọ, sọ pe, “Oriṣiriṣi egboogi oloro ati igbo la ka mọ wọn lọwọ.”
O ni awọn araalu lo ta wọn lolobo nipa iwa buruku t'awọn eeyan naa n hu niluu Ejigbo, ijọba ibilẹ Ejigbo nipinlẹ naa.
“Nigba ti wọn ta wa lolobo nipa buba awọn to n ta igbo niluh Ejigbo, nibi ti oniruuru egboogi oloro wa. Awọn ẹṣọ aabo Amọtẹkun gbera lọ sibẹ lati lọ koju wọn, ti ọwọ si tẹ wọn pẹlu egboogi oloro.
“Wọn ti n ṣe iranwọ fun wa lati le jẹ ki ọwọ tẹ awọn yooku ti wọn na papa bora.”
Siwaju sii, ọga agba naa tun ṣalaye pe ọwọ tẹ Ṣogo Oriade, ọmọ ọgbọn ọdun ati Aṣimiyu Tọheeb, ọmọ ọdun mejidinlọgbọn lagbegbe Oke-Onitea niluu Oṣogbo.
O jẹ ko di mimọ pe awọn eeyan naa ti kọkọ na papa bora tẹlẹ, ṣugbọn t'awọn ṣiṣẹ iwadii ijinlẹ ko to di pe ọwọ palaba wọn segi
“Lasiko ifọrọwanilẹnuwo, awọn afurasi naa jẹwọ nipa iwa idigunjale ati awọn ẹṣẹ iwa ọdaran miran ti wọn ti hu. A ti bẹrẹ igbesẹ ofin,” Ọmọyẹle sọ bẹẹ.
O wa rọ awọn eeyan lati maa wa ni ifura ni gbogbo igba nipa, ki wọn si maa fi to awọn agbofinro leti.
No comments:
Post a Comment