Gbogbo eto lo ti pari bayii fun eto ayẹyẹ iwuye amugbalẹgbẹ pataki fun gomina ipinlẹ Kwara lori eto iroyin igbalode Kọmureedi Olayinka Fafoluyi tọpọ mọ si Solace gẹgẹ bi Akewejẹ tiluu Aran-Ori.
Ọba Joseph Oyeyipo Babalola to jẹ Olu tiluu Aran-Ori to wa nijọba ibilẹ Irepodun, ipinlẹ Kwara lo fi Solace jẹ Akewejẹ ilu naa.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Fafoluyi ni wọn yan fun ipo tuntun yii latari awọn ipa ribiribi to ti ko ninu idagbasoke ilu naa, paapaa ipinlẹ Kwara lapapọ.
Gbagede ọgba ile ẹkọ alakọbẹrẹ tiluu Aran-Ori ni eto ọhun yoo ti waye lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹsan, oṣu yii.
Solace, nigba to n sọrọ ninu atẹjade to fi sita, o ni eto ọhun yoo gbọmọ pọn pẹlu boun tun ṣe fẹẹ ṣi awọn akanṣe iṣẹ tuntun toun ṣe lorukọ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq.
Lara awọn iṣẹ akanṣe naa ni Omi ẹrọ igbalode, ina agboorun ti a mọ si Solar mejilelọgbọn ati gbọngan awọn agunbanirọ olowo iyebiye to kọ lorukọ Gomina AbdulRazaq, iyẹn AbdulRahman AbdulRazaq Corpers' Lodge, to wa niluu Aran-Orin.
"Ko si eyikeyi ninu awọn akanṣe iṣẹ yii to le yọri si rere lai si ọga mi ati awokọṣe mi, Ọlọlajulọ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, ẹni to ko ipa ribiribi nigbesi aye mi," Fafoluyi sọ bẹẹ.
No comments:
Post a Comment