Ẹgbẹ CAN fi oye 'Knight of Faith' da alaṣẹ Adron Homes lọla - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 8, 2025

Ẹgbẹ CAN fi oye 'Knight of Faith' da alaṣẹ Adron Homes lọla


Ẹgbẹ ẹlẹsin Kristẹni lorileede Naijiria, Christian Association of Nigeria, ẹka ti ẹkun Iwọ Oorun ti fi oye Ajagun Igbagbọ, iyẹn “Knight of Faith” da alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes, Aarẹ Adetola EmmanuelKing lọla.

Igba akọkọ ree ti ajọ CAN yoo maa fi oye naa da ẹnikẹni lọla.

Kii ṣe pe ajọ CAN deedee yan Aare EmmanuelKing gẹgẹ bi ajagun igbagbọ tuntun, bi ko ṣe awọn ipa to jọju ti wọn ni ogbontarigi oniṣowo naa ti ko lagboole Kristẹni lo fa a, ti wọn fi loun ni ipo ọhun tọ si.

CAN jẹ ko di mimọ pe agba oniṣowo naa ti ko ipa manigbagbe lorileede Naijiria, leyi to n mu ki ilẹ naa tẹsiwaju 

Ilu Abẹokuta tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun ni eto ọhun ti wọn pe akori rẹ ni "Celebrating Distinction and Faithful Stewardship," to waye laipẹ yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI