Ẹsẹ ko gbero nile ẹkọ alakọbẹrẹ tiluu Aran-Orin to wa nijọba ibilẹ Irẹpọdun, ipinlẹ Kwara lọjọ Aje, Mọnde ana, nibi eto ayẹyẹ iwuye amugbalẹgbẹ pataki fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara lori eto iroyin igbalode, Ọlayinka Michael Fafoluyi, gẹgẹ bi Akewejẹ tiluu Aran-Orin.
Ọba Joseph Oyedipo Babalọla, Alaran tiluu Aran-Orin lo fi oye naa da Fafoluyi tọpọ awọn eeyan mọ si Solace lọla, latari awọn ipa ribiribi to ti ko ninu idagbasoke ilu naa, ati ipinlẹ Kwara lapapọ.
Nibi eto ayẹyẹ iwuye naa ni Ọba Alaran ti fi imọriri han si amugbalẹgbẹ pataki naa lori awọn iṣẹ akanṣe to jọju, eyi to ṣe siluu naa, pẹlu irolagbara awọn ọdọ.
Bakan naa ni Kabiyesi wa rọ Akewejẹ tuntun naa lati maa tẹsiwaju ninu awọn iṣẹ to ti dawọ le, eyi to fi n ṣaanu awọn eeyan kaakiri lai wo ti ipo oṣelu ati ẹlẹyamẹya.
Siwaju sii, Olomu tiluu Omu-Aran, Ọba Abdulraheem Ọladele Adeoti, gbe oṣuba kare fun ti ipa to n ko ninu idagbasoke ipinlẹ naa kaakiri, to si jẹ ko di mimọ pe iwa rẹ lo jẹ ki Gomina AbdulRazaq yan an gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ.
Lara awọn akanṣe iṣẹ ti amugbalẹgbẹ naa ṣiṣọ loju rẹ ni ina agboorun mejilelọgbọn kaakiri adugbo to wa niluu naa, ati ifilọlẹ ipilẹ ile awọn agunbanirọ to sọ lorukọ ọga rẹ, AbdulRahman AbdulRazaq Corpers' Lodge.
Ọpọ awọn alẹnulọrọ kaakiri ẹka igbe aye bii awọna ṣofin ipinlẹ Kwara, awọn alaga ẹgbẹ oṣelu, awọn ọba alaye, oloṣelu, oṣere tiata, to fi mọ awọn alẹnulọrọ ni Naijiria.
No comments:
Post a Comment