Ijọba apapọ ilẹ Naijiria ti kede Ọjọbọ, ọsẹ yii, ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun 2025 gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.
Minisita f'ọrọ eto abẹle Ọnarebu Olubunmi Tunji-Ojo lo sọrọ naa di mimọ lọjọ Aiku, ọjọ kẹjọ, oṣu yii.
Ijọba apapọ kede isinmi naa lati fi saami ayẹyẹ ọjọ eto oṣelu awa-arawa lorileede ọhun.
Eyii ti jẹ ki ilẹ Naijiria ni isinmi ọlọjọ meji laaarin ọsẹ kan, leyi ti ọjọ Aje jẹ ọjọ isinmi fun ayẹyẹ ọdun Ileya ti ijọba ti kede tẹlẹ.
Ninu atẹjade ti akọwe agba nile iṣẹ ijọba to n ri sọrọ ohun abẹle, Magdalene Ajani fi sita laipẹ yii, Tunji-Ojo gbe oṣuba kare fawọn ọmọ Naijiria bi wọn ti n ṣe ijọba alagbada lati ọdun mẹrindinlọgbọn sẹyin.
“Ọjọ kejial, oṣu Kẹfa duro fun itan irin ajo to n gbe orileede ti otitọ ati ẹtọ n jọba, ati eyi ti ifọkanbalẹ n duro, leyi to n ṣe aridaju ọjọ iwaju rere.
“Ọdun mẹrindinlọgbọn sẹyin n sọ itan ifarada, okin ati igboya ati ireti atunṣe ju ti tẹlẹ lọ,” Minisita naa sọ eyi.
No comments:
Post a Comment