Ẹgbẹ oṣelu ADC lawọn yoo gbajọba lọwọ APC lọdun 2027 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 6, 2025

Ẹgbẹ oṣelu ADC lawọn yoo gbajọba lọwọ APC lọdun 2027

Ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), ẹka tipinlẹ Ogun l'Ọjọru, ọsẹ yii ti sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati gbajọba lọwọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC to n ṣakoso lọwọ.

ADC sọ pe gbogbo ohun ti yoo ba gba lawọn yoo ṣe lati rii pe ipo gomina ja mọ ẹgbẹ naa lọwọ, nitori tawọn ti bẹrẹ oniruuru igbesẹ ti yoo fun wọn ni anfaani lati jawo olubori ninu eto idibo ọdun 2027.

Nibi ipade awọn alẹnulọrọ ati agbaagba lawọn ẹgbẹ oṣelu kaakiri, eyi to waye ni ile ẹgbẹ naa to wa lagbegbe Itoko niluu Abẹokuta ni ọrọ ọhun ti jẹyọ.

Alaga ẹgbẹ naa, Ọtunba Fẹmi Ṣoluade, jẹ ko di mimọ pe kaakiri ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria, to fi mọ ilu Abuja ni ipade ti wọn ṣe naa ti waye, kii ṣe ipinlẹ Ogun nikan.

O lawọn ti bẹrẹ oṣelu abẹle lati maa bawọn eeyan sọrọ, ati pe awọn n woye lati darapọ pẹlu awọn ẹgbẹ oṣelu miran, ki erongba wọn le wa si imuṣẹ.

O lawọn ko nii fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ oṣelu ọdun 2027, nitori pe gbogbo awọn ohun to jẹ aṣiṣẹ ti wọn ti ṣe sẹyin lawọn ti ri, tawọn si ti bẹrẹ iṣẹ lori rẹ.

Bakan naa lo sọ pe kii ṣe pe awọn fẹẹ gbajọba kaakiri Naijiria nikan, bi ko ṣe lati mu orileede Naijiria pada bọ sipo to yẹ.

Ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ naa, Oloye Rasaq Eyiowuawi to tun sọrọ jẹ ko di mimọ pe pipapọ ẹgbẹ yoo ṣe iranwọ pupọ fun wọn lati le ṣe aṣeyọri.

Eyiowuawi wa rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa lati ri iṣẹ naa gẹgẹ bi ajọṣe, nitori pe kii ṣe iṣẹ ti ẹnikan le da ṣe, bi ko ṣe pe ifọwọsowọpọ lo le mu wọn de ilẹ ileri.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI