Ileya: Ẹ jẹ ka ṣe otitọ pẹlu Ọlọrun ati ilẹ baba wa - Gomina AbdulRazaq rọ awọn araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 6, 2025

Ileya: Ẹ jẹ ka ṣe otitọ pẹlu Ọlọrun ati ilẹ baba wa - Gomina AbdulRazaq rọ awọn araalu



Bi ayẹyẹ ọdun Ileya ṣe n lọ kaakiri agbaye, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti rọ awọn ẹlẹsin Islam, paapaa gbogbo araalu lati maa ṣe otitọ pẹlu Ọlọrun ati ilẹ Naijiria.

Gomina AbdulRazaq lo sọ eyi ninu atẹjade to fi ki gbogbo Musulumi fun ti ayẹyẹ ọdun Ileya to n lọ lọwọ.

Bakan naa ni Gomina AbdulRazaq tun ki  Emir tiluu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari, fun ayẹyẹ naa.

Ninu atẹjade ọhun ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi ranṣẹ s'awọn akọroyin, AbdulRazaq ni ayẹyẹ ọdun Ileya jẹ asiko lasiko ko ere gbogbo iwa ifarada ati otitọ si Ọlọrun, to fi mọ aṣeyọri si imulẹ atokewa ti awọn ojiṣẹ bii Ibrahim ati Muhammad fi lelẹ.

AbdulRazaq wa gbadura pe gbogbo eeyan ni yoo ṣe ọpọ ọdun naa laye ati laaye rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI