...Miliọnu mẹtalelogun aabọ naira lo ti lu jibiti rẹ
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2025 ni ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu nilẹ Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka ti ẹkun ipinlẹ Ekoo akọkọ foju Ewulum Chimeze Felix ba ile-ẹjọ.
Ẹsun mọkanla ọtọọtọ ni ajọ EFCC fi kan Felix, eyi to nii ṣe pẹlu jibiti ayederu fisa, ti wọn si lo ti gba obitibiti owo lọwọ alaimọkan pẹlu ọgbọn alumọkọrọyi.
Miliọnu mẹtalelogun ataabọ naira ni EFCC sọ pe Felix ti gba lọwọ awọn onibara rẹ, pẹlu ẹtanjẹ wi pe oun yoo ba wọn gba fisa ilu oyinbo.
Iwaju Onidajọ Mojisọla Dada ti ile-ẹjọ ẹṣẹ ara-ọtọ, iyẹn Special Offences Court to wa lagbegbe Ikẹja ni Felix ti kawọ pọyin rojọ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni Felix ṣeleri lati ba ẹni to fẹsun kan an gba fisa ilẹ Gẹẹsi , iwe aṣẹ lati ṣiṣẹ ati iwe ẹri irin ajo.
Gbara ti Felix ti gba owo naa, la gbọ pe o ti bẹrẹ sii fi owo olowo jaye familete-ki-n-tutọ, ti ko si mu ileri rẹ ṣẹ, iyẹn lọdun 2024.
Orukọ ileeṣẹ Slenzy Ventures ni EFCC sọ pe Felix fi n lu awọn onibara rẹ ni jibiti, ti wọn si lo o gba miliọnu mejidinlogun naira lọwọ Nnochiri Chiedozie Boniface, pẹlu ẹtanjẹ.
Yatọ si eyi, wọn ni oriṣiriṣi ayederu iwe ni Felix tun ṣe jọ, koda to tun ni ayederu iwe awakọ ti ilẹ Florida, eyi ti orukọ VOJTISEK ADRIENA wa lori rẹ, eleyi ti wọn lo n lo lati fi lu awọn eeyan ni jibiti.
Gbogbo ẹsun ti EFCC fi kan Felix lo sọ niwaju ile-ẹjọ wi pe oun ko jẹbi wọn.
Bo tilẹ jẹ pe agbẹjọro EFCC, M. B. Isha, rọ ile-ẹjọ lati sun igbẹjọ siwaju, ati pe ki afurasi naa wa lọgba ẹwọn titi digba naa, sibẹ, agbẹjọro Felix, Michael O. Nwigbo, rọ ile-ẹjọ lati jẹ koun gba beeli onibara oun, ati pe yoo maa gba ile wa si kootu.
Onidajọ Dada wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, to si paṣẹ pe ki Felix wa lahamọ EFCC titi digba naa.
No comments:
Post a Comment