2027: Ajọ GoGA fontẹ lu Ambasidọ Ṣarafa Tunji Iṣọla lati di gomina l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 30, 2025

2027: Ajọ GoGA fontẹ lu Ambasidọ Ṣarafa Tunji Iṣọla lati di gomina l'Ogun


Ajọ kan ti wọn pe ara wọn ni Good Governance Advocate (GoGA) ni wọn ti sọ pe ẹni kan ṣoṣo t'awọn le fontẹ lu lati di gomina ipinlẹ Ogun lọdun 2027 ni aṣoju orileede Naijiria silẹ Gẹẹsi, Ambasidọ Ṣarafa Tunji Iṣọla.


Nibi ifilọlẹ ti ajọ naa ti ṣafihan Ṣarafa Iṣọla lọjọ Iṣẹgun, ana, eyi to waye ninu gbọngan ayẹyẹ Spices to wa ni Oke-Ilewo niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, ni wọn ti sọ pe ẹni t'awọn nigbagbọ ninu rẹ ni.

Wọn ni kii ṣe ahesọ wi pe eto oṣelu to n bọ lọdun 2027, awọn Ẹgba lo kan, ti awọn si nilo lati fontẹ lu oludije kan ṣoṣo.

Ambasidọ Mudaṣiru Ọlanrewaju to jẹ alakoso ajọ GoGA nipinlẹ Ogun, nigba to n sọrọ, o ni Tunji Iṣọla ni awọn ohun amuyẹ lati di gomina, ati pe o jẹ ọkan gboogi lara awọn oloṣelu ti ko lẹbọlẹru ni Naijiria.

Ọlanrewaju ni, nigba ti awọn n ṣagbeyẹwo gbogbo awọn to kaju oṣuwọn lati jade fun ipo gomina lọdun 2027, paapaa lati ẹkun Ẹgba, ọkunrin naa to ṣẹṣẹ gbe ipo silẹ gẹgẹ bi aṣoju Naijiria silẹ Gẹẹsi ni.

O sọ siwaju pe Tunji Iṣọla kii ṣe atọhuntinwa, ati pe ẹni to ni okun nidi ni, ti ko si si ninu awọn ti ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu, EFCC ti fẹsun kan.

"Bi a ba n sọ nipa awọn ti oye iṣejọba ye, Tunji Iṣọla ko lẹlẹgbẹ, nitori to ti ṣe alaga ijọba ibilẹ ri, o ti ṣe alaga ẹgbẹ ijọba ibilẹ lẹkun Guusu Iwọ Oorun Naijiria ri, bẹẹ lo tun ti ṣe akọwe ijọba ipinlẹ, minisita, to fi mọ aṣoju agbaye ti a mọ si Ambasidọ," Ọlanrewaju sọ eyi.

Nigba to n fi imọriri han si awọn alakoso ajọ GoGA, Ambasidọ Ṣarafa Tunji Iṣọla dupe gidigidi lori bi awọn eeyan naa ṣe fontẹ lu oun, to si ṣeleri pe oun ko nii ja wọn kulẹ.

Tunji-Iṣọla ni asiko oṣelu to wa nita yii, ki awọn eeyan ma ṣe jẹ ki awọn oloṣelu onirọ fi owo tan wọn jẹ, nitori pe bi wọn ba ti na owo, ọna lati ri owo naa pada ni wọn yoo maa wa, eyi ti yoo jẹ ki wọn pa ojuṣe wọn ti.

O ni lotitọ loun ni iriri iṣakoso ijọba, nitori toun ti ṣiṣẹ nijọba ibilẹ, ipinlẹ, orileede ati agbaye, ati pe oye iṣejọba ye oun yekeyeke.

Bakan naa lo ni ki ẹnikẹni ma ṣe tẹti si awọn ọrọ oṣelu ti awọn alatako n gbe kaakiri nipa oun, ati pe ọna lati ba orukọ oun jẹ ni wọn n wa, toun ko si nii gba fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI