Tunji-Iṣọla di alaga eto ayẹyẹ ileeṣẹ Penpushing l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 28, 2025

Tunji-Iṣọla di alaga eto ayẹyẹ ileeṣẹ Penpushing l'Ogun


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun Aṣoju ilẹ Naijiria si ilẹ Gẹẹsi nigba kan ri, Ṣarafa Tunji Iṣọla lati di alaga eto ayẹyẹ ileeṣẹ Penpushing to wa nipinlẹ Ogun.

Eto ọhun, ẹlẹẹkeje iru rẹ ti wọn pe akori rẹ ni ‘‘Reworking Nigeria’s Federalism, Perspectives to Restructuring The Future on Fiscal Federalism’’ ni yoo waye ninu gbọngan ile ikawe Olusegun Obasanjo, OOPL to wa niluu Abẹokuta.

Deedee agogo mẹsan owurọ ni eto naa yoo bẹrẹ l'Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ yii, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2025.

Oludasilẹ ajọ UN Capital Africa, Ọmọwe Oby Ezekwesili ni yoo la gbọ pe yoo ṣe idanilẹkọọ fawọn alejo, nigba ti Ebumawe tiluu Agọ Iwoye, Ọba Oba Abdul-Razaq Adenuga yoo jẹ oba alaye ọjọ naa.

Taa ni Sarafa Tunji-Isola

Ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 1960 ni wọn bi Tunji-Isola, akẹkọọ ile-ẹkọ Chartered Institute of Marketing, to wa ni England, nibi to ti pari lọdun 1981.

Tunji-Isola lọ si ile-ẹkọ ijọba ti Harvard Kennedy to wa ni USA, ati fasiti.

Ọdun 1983 lo bẹrẹ iṣẹ olukọni nile ẹkọ awọn olukọni tipinlẹ Katsina.

Wọn dibo yan Tunji-Isola gẹgẹ bi alaga ijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta lọdun 1997, bẹẹ ni wọn tun yan an gẹgẹ bi alaga igbimọ awọn alaga ijọba ibilẹ nipinlẹ Ogun, bẹẹ lo tun di alakoso ijọba ibilẹ lẹkun Guusu Iwọ Oorun Naijiria.

Lọdun 2002, ilẹ Amẹrika ranṣẹ pe Ambasidọ Iṣọla fun irin ajo iwe kika nipasẹ eto ti wọn pe ni International Visitors Programme.

Ambasidọ Tunji Isola di akọwe ijọba ipinlẹ Ogun lọdun 2003 labẹ iṣakoso Otunba Gbenga Daniel, ẹni to tun ti di Sẹnetọ bayii.

Bakan naa lọdun 2007, wọn yan Ambasidọ gẹgẹ bi minisita f'ọrọ ohun amuṣọrọ Naijiria, ko to di pe wọn tun yan an lati di aṣoju ilẹ Naijiria si ilẹ Gẹẹsi lọdun 2021.

Ọkan pataki lara awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ oṣelu APC ni Tunji Isola, ẹni to n foju sọna lati jade fun ipo gomina ipinlẹ Ogun lọdun 2027.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI