Lẹyin ọdun meje, Akinlade pada sẹgbẹ oṣelu APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 30, 2025

Lẹyin ọdun meje, Akinlade pada sẹgbẹ oṣelu APC


'Kaabọ, ṣe daadaa lo de, a ti n reti rẹ o, kaabọ', lorin ti ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Ogun n kọ fun oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Peoples Movement, APM lọdun 2019, Onarebu Adekunle Abdulkabir Akinlade nigba to n jẹ ko di mimọ pe oun ti pada sẹgbẹ naa.

Oni Ọjọru tii se Wẹside ni Akinlade, ẹni to tun jẹ igbakeji oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu lọdun 2023 pada si APC pẹlu awọn alatilẹyin rẹ.

Yatọ si Adebutu, awọn to tun kọwọrin pẹlu rẹ lọ si APC ni alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun tẹlẹ, Ọnarebu Sikirulai Ogundele; Ọnarebu Luqmọn Atọbatẹlẹ to jẹ ọmọ ile igbimọ asọfin lẹgbẹ alatako; ati ọmọ ile igbimọ asọfin tẹlẹri, Idowu Olowofuja.

Awọn miran ni alaga ajọ to n ri sọrọ ijọba ibilẹ tẹlẹri, Ọnarebu Rotimi Rahaman; Ọmọwe Mọjeed Ekelojumati ati ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọmọ ẹyin wọn.

Fun awọn ti ko ba gbagbe, inu ẹgbẹ oṣelu APC ni Ọnarebu Akinlade tọpọ tun mọ si 'Triple A' wa tẹlẹ, ṣugbọn ọrọ tikẹẹti to ja mọ Gomina Dapọ Abiọdun lọwọ, lo jẹ ko dero ẹgbẹ oṣelu APM lọdun 2018.

Gomina Abiọdun nigba to n gba wọn wọle, o ni gbogbo iranwọ ti wọn ba nilo ni ẹgbẹ naa yoo fun wọn gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ.

"Mo fẹẹ fi da a yin loju pe a maa fun yin ni gbogbo ẹtọ, anfaani ati ibọwọfun to tọ sii yin," Gomina Abiọdun fọkan wọn balẹ.

Bakan naa lo tun ṣapejuwe ẹgbẹ oṣelu PDP gẹgẹ bi korofo ẹyin ti ko ni nnkankan ninu mọ, pẹlu bi ọpọ ọmọ ẹgbẹ wọn ṣe n darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu miran.

O ni inu oun dun wi pe Ọnarebu Akinlade ati awọn yooku ti kuro ninu ọkọ oju omi to n ri, lati darapọ mọ APC.

Nibẹ ni gomina ti rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kaakiri wọọdu to wa nipinlẹ Ogun lati tẹwọ gba gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun gẹgẹ bii mọlẹbi.

"Lonii, awọn eeyan wa ti pada wa sile, inu wa si dun, a n yọ ninu rẹ. Idunnu lo jẹ fun wa lati gba wọn wọle," Abiọdun sọ bẹẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, Akinlade sọ pe ni bayii toun ti pada sinu ẹgbẹ APC, oun yoo ko ipa oun pada gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ lati rii pe itẹsiwaju de ba ipinlẹ naa ati orileede lapapọ.

O wa dupẹ lọwọ gomina ati awọn ọmọ ẹgbẹ naa fun bi wọn ṣe gba wọn tọwọ-tẹsẹ pads sinu ẹgbẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI