Gomina AbdulRahman Abdulrazaq tipinlẹ Kwara ti kẹdun iku Awujalẹ tilẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Kayọde Adetọna gẹgẹ bi adanu nla fun ilẹ Naijiria.
Ninu atẹjade ti gomina buwọ lu, eyi ti akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye fi sita, o ni adari to duro gẹgẹ bi apejuwe iṣọkan ati ibọwọfun.
Gomina AbdulRazaq gbe oṣuba kare fun ọkan ifọkansin ati ifarajin ti Awujalẹ fi dari awọn eeyan rẹ nilẹ Ijẹbu, ati bo ṣe yi itan aṣa ati iṣẹṣe ilẹ naa pada lara ọtọ.
O wa ba Gomina Dapọ Abiọdun ati gbogbo ọmọ Ijẹbu kẹdun lapapọ, to si gbadura pe ki Ọlọrun tẹ oku rẹ si afẹfẹ rere.
No comments:
Post a Comment