Dangote lo sọrọ naa ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọhun, Anthony Chiejina fi sita lọjọ Ẹti, ọsẹ yii.
O ni oun ti fẹyinti gẹgẹ bi alakoso agba ati alaga igbimọ iṣakoso ileeṣẹ naa, bẹrẹ lati ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2025.
Atẹjade naa sọ pe Aliko Dangote yoo gbajumọ ọrọ ileeṣẹ ifọpo, epo rọbii, ajilẹ ati ibaṣepọ pẹlu ijọba, lati le gbe ileeṣẹ naa goke agba laarin adehun ọdun marun-un to wa nilẹ.
Siwaju sii lo ṣalaye pe Ọgbẹni Emmanuel Ikazoboh ni yoo tẹsiwaju ipo toun fi silẹ naa, ti yoo si maa ṣakoso gẹgẹ bi adari tuntun.
Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe Hajiya Mariya Aliko Dangote ni wọn ti yan gẹgẹ bi alaga igbimọ iṣakoso ileeṣẹ naa, ni kete ti Ọjọgbọn Dorothy Ufot fẹyinti ninu igbimọ iṣakoso.
No comments:
Post a Comment