Ilẹ idọti kiko gbọna ara yọ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 26, 2025

Ilẹ idọti kiko gbọna ara yọ ni Kwara


Lojuna lati jẹ ki imọtoto wa kaakiri ipinlẹ Kwara, ki awọn araalu naa le si wa ni ilera pipe, ijọba ipinlẹ naa ti ṣagbekalẹ ilana tuntun lati maa ko awọn ilẹ idọti danu.
 
Apoti idalẹnu-si igbalode ti ko din ni aadọrin nijọba ipinlẹ naa ti ra lati pin kaakiri fun irọrun araalu.

Yatọ si eyi, awọn ọkọ nla-nla idalẹsi marun-un ọtọọtọ nijọba tun ti ra, eyi ti yoo maa lọ kaakiri lati ko awọn idọti danu.

Labẹ eto ti wọn pe ni Agro-Climatic Resilience in Semi-Arid Landscapes (ACReSAL) Project, ti wọn gbe kalẹ lati maa mu idagbasoke ba eto imọtoto ayika ati agbegbe nijọba ti ra awọn irinṣẹ igbalode naa.

Ileeṣẹ to n mojuto ayika ati agbegbe nipinlẹ Kwara, eyi to wa niluu Ilorin ni ifilọlẹ naa ti waye lọjọ Ẹti to kọja.

Nigba to n sọrọ, Kọmiṣanna feto ayika ati agbegbe, Hajia Nafisat Musa-Buge nigba to n gba ẹnu Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọrọ, ṣalaye pe igbesẹ naa wa lara awọn ọna lati dẹkun ajakalẹ arun ati omiyale.

O ni wọn yoo kọ awọn apoti idalẹsi naa s'awọn agbegbe to yẹ, nibi ti araalu yoo maa gbe ilẹ ayi idọti wọn lọ lati da a si, ko to di pe awọn ọkọ idasilẹnu naa lọ pati gbe wọn.

O wa rọ araalu lati maa tẹle ilana nipa ṣiṣamulo awọn apoti idalẹsi naa, ki wọn si yago fun iwa aini imọtoto.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI