Ọjọ Aiku ana, ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun 2025 ni Buhari dagbere faye nile iwosan kan to wa niluu London, ilẹ Gẹẹsi.
"Ẹgbẹ gomina Naijiria (NGF) gba iroyin ibanujẹ nipa iku Aarẹ ana, Muhammadu Buhari to ku si London lojo Aiku ọjọ kẹtala oṣu Keje ọdun 2025," atẹjade ti alaga ẹgbẹ naa, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara buwọ lu sọ bẹẹ.
Siwaju sii ni NGF jẹ ko di mimọ pe Muhammadu Buhari kii ṣe aarẹ tẹlẹri tabi oloro ologun tẹlẹri lasan, o tun jẹ aṣiwaju nidi oṣelu apapọ to n fun awọn ọmọ ẹyin rẹ ni iwuri, to si n fi iwa rere kọ wọn.
"A ma maa ranti rẹ pẹlu iwa irẹlẹ, ọkan suuru ati igbe aye to yatọ si rere," wọn fi kun ọrọ wọn.
Ẹgbẹ gomina Naijiria wa ba Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, iyawo rẹ, Aisha Buhari ati mọlẹbi, to fi mọ gbogbo ọmọ ilu Daura ati Naijiria lapapọ kẹdun iku oloogbe naa.
No comments:
Post a Comment