Wọn ti dajọ iku fawọn to pa Sọfiat, ọmọdun mẹrindinlogun l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 14, 2025

Wọn ti dajọ iku fawọn to pa Sọfiat, ọmọdun mẹrindinlogun l'Abẹokuta

Idunnu nla lo jẹ fun mọlẹbi ọmọdebinrin kan, Sọfiat Ọkẹowo tawọn amookunṣeka pa danu lati fi ṣetutu owo lọdun 2022, nigba ti ile-ẹjọ giga nipinlẹ Ogun paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun wọn.

Ọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja yii, ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 2025 ni ile-ẹjọ sọ pe awọn mẹta ti wọn jẹbi ẹsun ipaniyan naa ko yẹ lati maa gbe laarin ilu pẹlu awọn eeyan gidi.

Bi ẹ ko ba gbagbe, gbogbo ilu Abẹokuta lo mi titi lọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2022, nigba ti aṣiri awọn ọmọdekunrin mẹrin kan tu nibi ti wọn ti n jo ori oku Sọfiat Pẹlumi Ọkẹowo lagbegbe Oke-Arẹgba niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Awọn ọlọdẹ agbegbe Oke-Arẹgba la gbọ pe aṣiri awọn ọmọdekunrin mẹrin naa tu si lọwọ nibi ti wọn ti n jo ori oku Sọfiat ti wọn lo n kọ iṣẹ telọ lọwọ.


Wariz Ọladẹhinde, ọmọ ọdun mẹtadinlogun; Sọliudeen Majẹkodunmi, ọmọ ọdun mejidinlogun; Abdulgafar Lukman, ọmọ ọdun mọkandinlogun ati Mustakeem Balogun, ọmọ ogun ọdun ti wọn loun ni Sofiat n fẹ, ni awọn mẹrẹẹrin tọwọ tẹ.

AWIKONKO rii gbọ pe nnkan bi agogo mẹfa irọlẹ kọja iṣẹju diẹ, ọjọ naa ni ẹnikan pe Sọfiat lori foonu wi pe ko maa sare bọ, ati pe ko gbọdọ dagbere fẹnikẹni. Wọn ni ile ni Sọfiat wa ladugbo Idi-Apẹ, to si n dana ounjẹ alẹ, iyẹn Ẹwa lọwọ lakoko naa, ko to di pe o fi silẹ lọ ba ẹni to pe e lagbegbe Oke-Arẹgba.

Ẹgbọn rẹ kan, Muinat Ọkẹowo la gbọ pe o wa nibẹ lakoko naa, ẹni yii si ni Sofiat sọ fun pe ko maa ba oun wo Ẹwa naa, nitori toun fẹẹ sare de ibi kan, ṣugbọn ti ko sọ ibi to n lọ, iyẹn ni nnkan bi agogo meje ku iṣẹju meloo kan.

Lẹyin bi ọgbọn iṣẹju si wakati kan, iyẹn lẹyin ti Ẹwa naa jinna tan, ti wọn ko ri Sọfiat ko pada sile, ni nnkan bi agogo mẹjọ la gbọ pe Muinat, ẹgbọn Sọfiat yii pe lori foonu lati beere ibi to wa, ṣugbọn ti wọn lo sọ pe oun n bọ laipẹ, ti ko si sọ ibi to wa.

Sọfiat ni wọn reti titi di nnkan bi agogo mẹwaa alẹ ọjọ naa, ti wọn ko si tun rii ko pada sile, eyi ti wọn sọ pe kii ṣe bẹẹ tẹlẹ. Asiko naa ni wọn tun pe foonu rẹ, ṣugbọn ti ko lọ mọ. Gbogbo erongba ẹgbọn rẹ yii ni pe boya foonu rẹ ti ku, bo tilẹ jẹ pe ọkan wọn ko balẹ.


Si iyalẹnu nigba ti wọn maa pada gburo Sọfiat, iroyin oku rẹ ni wọn gbọ laarọ ọjọ keji tii ṣe Abamẹta.

Gbogbo asiko ti a gbọ pe awọn obi Sọfiat n reti nile yii, wọn ni ololufẹ rẹ, Mustakeem Balogun at'awọn ọrẹ rẹ n ṣe ipalẹmọ bi wọn yoo ṣe pa a danu, ti wọn yoo si fi ṣoogun owo.

Waris Ọladẹinde ni ile ẹjọ pada fi silẹ lọjọ kejilelogun, oṣu kẹta, ọdun 2022, pẹlu bi ile-ẹjọ ṣe sọ pe ko si ẹri to fidi rẹ mulẹ pe ọmọ naa wa ninu awọn to pa Sọfiat, ati pe ofin ko le fi iya jẹ alaiṣẹ.

Ile-ẹjọ lọjọ Ẹti to kọja yii paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun Mustakeem ati Sọliudeen, nigba to sọ pe ki Lukman dero ẹwọn gbere pẹlu iṣẹ aṣekara.


Kọmiṣanna feto idajọ nipinlẹ Ogun, Onidajọ Oluwaṣina Ogungbade, nigba to n sọrọ lori idajọ naa, jẹ ko di mimọ pe aṣeyọri nla ni ipinlẹ naa ṣe lori idajọ to waye, ati pe awọn tọrọ naa kan ni wọn ko tun le gbe ni ipejọpọ awọn eeyan gidi mọ lailai.

“Inu wa dun wi pe a pari ẹjọ yii, eyi to fọkan mọlẹbi Sọfiat balẹ pe idajọ ododo pada waye. Iwuri nla lo jẹ fun mi wi pe ileeṣẹ eto idajọ pada ṣe aṣey]ori pẹlu oniruuru adojukọ ti wọn ba pade,” Kọmiṣanna feto idajọ sọ bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI