Igbakeji aarẹ ilẹ Naijiria, Kashim Shettima ni iroyin fi to wa leti o ti niluu London, ilẹ Gẹẹsi lati gbe oku Aarẹ ana, Muhammadu Buhari pads si Naijiria.
Irọlẹ oni, ọjọ Aje ni wọn yoo sinku Aarẹ Buhari nile rẹ to wa niluu Daura, ipinlẹ Katsina.
Ọsan ọjọ Aiku to kọja, ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun 2025 ni Aarẹ Buhari dagbere faye lẹni ọdun mejilelọgọrin.
Buhari di Aarẹ Naijiria laarin ọdun 2015 si 2023, ko to gbe ijọba silẹ. Bẹẹ lo tun ti figba kan ri jẹ olori orileede lasiko ologun.
Fun igba pipẹ ni Buhari ti n koju aisan kan ti ko sọ sita, koda gẹgẹ bi aarẹ Naijiria, ko to di pe ẹlẹmi pada gba a.
Nigba to n fi iroyin naa lede, agbẹnusọ Shettima, Stanley Nkwocha jẹ ko di mimọ pe igbakeji aarẹ ti wa ni ile iwosan ti Aarẹ Buhari ku si, ati pe minisita f'ọrọ ilẹ okeere, Yusuff Tuggar lo gba Shettima lalejo.
No comments:
Post a Comment