Ẹgbẹ 'Ogun Visionaries' rawọ ẹbẹ si Sẹnetọ Yayi lati jade du ipo gomina lọdun 2027 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 9, 2025

Ẹgbẹ 'Ogun Visionaries' rawọ ẹbẹ si Sẹnetọ Yayi lati jade du ipo gomina lọdun 2027

Lọjọ Iṣẹgun, Tuside, ana ni ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni Ogun Visionaries sọrọ sita wi pe awọn ṣetan lati ṣagbatẹru Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo Yewa nile igbimọ aṣofin agba ni Naijiria, Solomon Ọlamilekan Adeọla fun ipo gomina lọdun 2027.

Ẹgbe naa ti wọn ṣe ifilọlẹ rẹ ninu ọgba awọn akọroyin to wa niluu Abẹokuta ni wọn ti sọ pe gbogbo eto lawọn ti bẹrẹ lati rii pe ipo naa ja mọ Sẹnetọ Adeọla tọpọ mọ si Yayi lọwọ.

Alakoso ẹgbẹ naa, Ọnarebu Lẹyẹ Ọdunjọ nigba to n sọrọ, o ni asiko naa ree ti gbogbo ọmọ Yewa ni lati fi ohun ṣọkan, lati le jẹ ki wọn de ipo akọkọ nipinlẹ Ogun lọdun 2027, eyi ti wọn ti n le lati ọdun 1976 ti wọn ti da ipinlẹ naa silẹ.

''Ẹkun Yewa Awori ko tii fohun ṣọkan nitori iwa imọ-tara ẹni nikan ti awọn adari, ifẹ ọkan ati aisi ẹni ti yoo lewaju. Bi 2027 ṣe n sunmọ, ẹkun Yewa Awori ti wa ni asiko lati fimọ ṣọkan, ki wọn si panupọ lori irin ajo oṣelu,'' Ọdunjọ sọ bẹẹ. 

O ni erongba lati fa gomina kalẹ ti doju rẹ bayii, ti wọn si ti to asiko, ati pe asiko ti awọn gbọdọ lo imọ ati oye lati gba ipo akọkọ nipinlẹ Ogun.

''Asiko naa ree ti a ni lati ṣe otitọ pẹlu ara wa, ka si la ara wa lọyẹ. Pẹlu bi a ṣe ni itan to kun fọnfọn, ti a si ni awọn ọmọwe pẹlu ẹkun to duro digbi, sibẹ, ẹkun Yewa Awori ko tii le fi ohun ṣọkan.''

Oo tẹsiwaju pe aile fimọ papọ lati fi ẹnu ko lori ohun kan ṣoṣo, jẹ nnkan to n fa ipenija ati ifasẹyin fun wọn lati fa gomina kalẹ.

''Ẹgbẹ Ogun Visionaries to nii ṣe pẹlu oṣelu, eyi to kaakiri ipinlẹ Ogun ti wa n pe wi pe ki ẹkun Iwọ Oorun ipinlẹ yii fa gomina kalẹ lọdun 2027. O jẹ ohun ibanujẹ wi pe ẹkun yii nikan ni wọn ko tii fa gomina kalẹ latigba ti wọn ti da ipinlẹ naa silẹ lọdun 2027.

''Fun idi eyi, a n sọ pe asiko naa ree lati fi ohun ṣọkan, ka si fimọ ṣọkan, ka le fa gomina kalẹ. Ẹgbẹ wa si ti parapọ pẹlu awọn to kaju oṣuwọn, lati rii pe a gbaruku ti ẹni kan ṣoṣo to kaju rẹ ni ẹkun idibo Yewa, Sẹnetọ Solomon Ọlamilekan Adeọla tọpọ mọ si Yayi.''

O wa dupẹ lọwọ Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu lori atilẹyin to n fun Sẹnetọ Yayi lati ibẹrẹ pẹpẹ titi di asiko to fi wa sipinlẹ Ogun, to si lawọn nigbagbọ pe yoo de ipo gomina.

O fi kun ọrọ rẹ pe latigba ti Yayi ti de sipinlẹ Ogun lo ti n ṣe oriṣiriṣi ironilagbara ati iranlọwọ fawọn araalu, ati pe kaakiri ẹkun mẹtẹẹta to wa nipinlẹ naa lo ti n ṣiṣẹ takuntakun.

Ọkan lara awọn agba ẹgbẹ naa, Ọnarebu Osu Adeniyi ṣalaye pe oloṣelu bii Yayi ṣọwọn nipinlẹ Ogun, nitori pe ẹni to n ṣeleri, to si n mu ileri ṣẹ ni.

''Nigba to jawe olubori lọdun meji sẹyin, Yayi loun yoo sọ ẹkun Yewa di ilu Oyinbo kekere, a si ti n ri ipa rẹ bayii, nitori pe yatọ si opopona to ja geere, o tun ṣe ina agboorun kaakiri opopona fun irọrun araalu. Pẹlu eyi, a nigbagbọ ninu rẹ.''

Bakan naa, Ọnarebu Lekuti ninu ọrọ tiẹ sọ pe awọn ko tun nilo lati jẹ ki ẹnikẹni sọ fun wọn pe Sẹnetọ Yayi nikan lo le dari ipinlẹ Ogun lọdun 2027, nitori pe o ti ṣe awọn ohun to foju han lati fọkan awọn araalu balẹ wi pe oun kaju oṣuwọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI