Ijọba ipinlẹ Ogun ti jẹ ko di mimọ pe wi pe ko si otitọ ninu iroyin kan ti wọn n gbe kaakiri wi pe ọkunrin kan, Ogbojionu Ogbonna ti wọn ṣẹṣẹ tu silẹ laipẹ yii ko mọ ohunkohun lori ẹsun ti wọn fi kan an, ati pe iya alaiṣẹ lo jẹ fun ọdun mejilelogun.
Ipinlẹ Ogun sọ pe iroyin ẹlẹjẹ ni bi wọn ṣe sọ nitori ẹsun wi pe Ogbonna ra ẹrọ amunawa jẹnẹretọ ti ẹnikan jigbe ni wọn ṣe ran an lẹwọn, bi ko ṣe pe ẹsun idigunjale ni wọn fi kan an.
Ninu atẹjade ti adajọ agba nipinlẹ Ogun, Oluwaṣina Ogungbade fi sita, o ni iroyin kan ti wọn gbe jade sọ pe Ṣẹgun Ajibade lorukọ ẹni to jale naa, ti wọn si ran an lẹwọn lọdun 2016, ṣugbọn ti wọn tun jẹ ko lo ọdun mẹsan miran lẹwọn.
Ogungbade ṣalaye pe irọ to jinna si otitọ ni oniroyin naa gbe jade sita, ati pe lati ṣi ọpọ eeyan lọkan ni, to si lo jẹ iyalẹnu.
Ijọba sọ pe ẹjọ iku ni ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ogun da fun Ogbonna lọjọ kẹrinla, oṣu kinni, ọdun 2003 lori ẹsun idigunjale, ṣugbọn ti wọn yi ẹjọ iku naa pada si ẹwọn gbere nigba ti Gomina Dapọ Abiọdun da si, nipa awọn to foju aanu wo.
Atẹjade naa tẹsiwaju pe ori tun ko Ogbonna yọ, pẹlu bo ṣe wa lara awọn Gomina Abiọdun tun foju aanu wo lati da silẹ nigba ti wọn n ṣayẹyẹ ọjọ iṣẹjọba-awa-ara-wa tọdun 2025.
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe oju aanu naa lo jẹ Aarẹ ati Gomina nikan ni wọn lẹtọọ sii lati da ẹlẹwọn silẹ, lori amoran ti igbimọ to n sọrọ titu ẹlẹwọn silẹ ba ti fun wọn, eyi ti adajọ agba ati kọmiṣanna feto idajọ jẹ alaga.
Nigba to n ṣalaye, Ogungbade sọ pe kii ṣe pe Ogungbade ra jẹnẹretọ ti wọn jigbe nikan, bi ko ṣe pe ko si ẹri aridaju nipa ọjọ to ra jẹnẹretọ ti wọn n sọrọ nipa rẹ yii.
O ni “Otitọ ibẹ ni pe ni nnkan bi agogo mẹwaa alẹ ọjọ kẹta, oṣu kẹwaa, ọdun 2000, ẹgbẹ adigunjale kan yawọ ile epo ELF to wa lopopona Abẹokuta siluu Ekoo, wọn si ji ẹrọ jẹnẹretọ to jẹ 10 KVA Lister.
“Awọn adigunjale naa bori awọn ọlọdẹ meji to n ṣọ ile-epo naa. Wọn fi irin fọ ọkan lara wọn, Yusuf Akanni lori ati ẹsẹ, wọn si kan ẹyin rẹ.
“Wọn tun fi irin naa fọ ọlọdẹ keji, Moses Bankọle lori, ti wọn si de awọn mejeeji mọlẹ.
“Nibẹ ni Moses Bankọle ku si, ko to di pe Ogbonna ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ ji jẹnẹretọ Lister naa gbe salọ.
”Yusuf Akanni, toun ko ba iṣẹlẹ naa lọ, lo jẹ ẹlẹri akọkọ fun ijọba ipinlẹ Ogun.
“Ogbonna jẹ mẹkaniiki to n tun jẹnẹretọ ṣe, oun si ni adigunjale to tu jẹnẹretọ naa, leyi to jẹ ki wọn rii jigbe nibi ti wọn gbe e si.
“Ko pẹ si asiko naa, ni nnkan agogo meji aabọ oru, lagbegbe Too Geeti Ọta, awọn ọlọpaa da ọkọ kan duro, eyi ti wọn fi ko igi ati baagi omi, mọto naa ni wọn fi gbe jẹnẹretọ nla kan.
“Jẹnẹretọ ọhun lo jẹ eyi ti wọn jigbe laipẹ si asiko naa ni ile-epo ELF. Ogbonna naa wa ninu ọkọ ọhun, pẹlu awakọ to n jẹ Sunday Oloyede, ati ẹnikan to n jẹ Kọlawọle Ọladeji.
“Nigba ti awọn ọlọpaa koju wọn, ko si ẹni to le sọ pato ibi ti wọn ti ri jẹnẹretọ naa, idi ree ti ọlọpaa fi gba mọto maa, ti wọn si mu gbogbo awọn to wa ninu rẹ.”
Siwaju sii lo ni awakọ naa ati Ọladeji na papa bora pẹlu ọkọ ọhun, ti wọn si fi Ogbonna silẹ. Ṣugbọn ṣa, o ni teṣan ọlọpaa to wa nitosi ni wọn ti ọkunrin naa mọ, to si salọ ki ilẹ too mọ.
Bakan naa lo ni ọlọpaa tọpinpin ẹni to ni ọkọ ọhun, ti ẹni naa ṣe atọna bi ọwọ ṣe tẹ gbogbo awọn awakọ rẹ, to fi mọ Ogbonna, ko to di pe wọn foju ba ile-ẹjọ
Ijọba ipinlẹ Ogun sọ pe Ogbonna jẹwọ lọna meji ọtọọtọ, koda ti ẹlẹri mọkanla tun farahan nile ẹjọ ko to di pe wọn dajọ iku fun un.
No comments:
Post a Comment