Gomina AbdulRazaq kẹdun iku Oludofian to waja ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 11, 2025

Gomina AbdulRazaq kẹdun iku Oludofian to waja ni Kwara


Gomina AbdulRahman Abdulrazaq ti kẹdun iku Oludofian tiluu Idofian nijọba ibilẹ Ifelodun, ipinlẹ naa.

Oludofian, Ọba Muhammed Jamiu Omikunle II lo jade laye l'Ọjọbọ to kọja yii lẹyin aisan rampẹ.

AbdulRazaq nigba to n ṣapejuwe ọba alaye to wa ni ipele keji awọn ọba, o ni eeyan to fẹran alaafia ati ilọsiwaju ilu Idofian  ni.

Gomina sọ pe adanu nla ni ipapoda ọba naa jẹ fun gbogbo ọmọ ati araalu naa, paapaa gbogbo ijọba ibilẹ Ifelodun.

Bakan naa ni gomina rọ gbogbo araalu lati mu ọkan le, ki wọn si duro ṣinṣin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI