Loni ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, NLC, ẹka tipinlẹ Ogun kede pe awọn ti bẹrẹ iyanṣẹlodi alailọjọ kaakiri ipinlẹ naa, latari bi ijọba ṣe kọ lati da wọn lohun lori ohun ti wọn n beere fun.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ pe oṣiṣẹ to ba lọ si ibi iṣẹ kan ṣe bẹẹ lapo ara rẹ ni, ati pe awọn ko nii da si ọrọ rẹ bi ohunkohun ba ṣẹlẹ sii.
Ninu atẹjade ti alaga ẹgbẹ naa, Kọmureedi Hameed-Benco Ademola fi sita lọjọ Aje, ọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 2025, o ni igbesẹ yii waye lẹyin ti ipade awọn pẹlu ijọba ipinlẹ Ogun fori ṣanpọn.
Ademọla sọ pe ohun ti awọn agbaagba nidi iṣẹ ijọba ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ wọn fẹnu ko le lori nibi ipade ti wọn ṣe ni gbagede Arcade to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta ni lati gunle iyanṣẹlodi alailọjọ.
Bakan naa, ninu atẹjade naa ti akọwe ẹgbẹ ọhun, Kọmureedi Christian Omoneh buwọ lu pẹlu alaga, wọn ni ko si gbọdọ si oṣiṣẹ to gbọdọ lọ sẹnu iṣẹ lai jẹ pe wọn gbọ lati ọdọ awọn alakoso ẹgbẹ NLC l'Ogun.
Bo tilẹ jẹ pe NLC ko ṣalaye nipa awọn nnkan ti wọn n beere fun ninu atẹjade ti wọn fi lede, sibẹ, wọn jẹ ko di mimọ pe awọn ṣetan lati jokoo pẹlu ijọba lati yanna-naa awọn ohun to n bi wọn ninu.
No comments:
Post a Comment