Awọn ile ẹkọ naa ti wọn ti dẹnukọlẹ lati ọdun pipẹ sẹyin la gbọ pe ijọba Kwara gbe dide, ti wọn sì kọ wọn lọna igbalode.
Igbesẹ yii lo wa lara awọn afojusun ati erongba ijọba ipinlẹ naa lati mu idagbasoke ba eto ẹkọ, ati lati jẹ ki awọn akẹkọọ lati ipinlẹ Kwara ba ẹgbẹ pe lagbaye.
Nibi ifilọlẹ naa to waye nile ẹkọ girama ti ECWA, eyi to wa lagbegbe Wokowomu niluu Omu-Aran, Kọmiṣanna f'ọrọ eto ẹkọ, Ọmọwe Lawal Olohungbebe, ki awọn ara agbegbe naa ku oriire itẹsiwaju to ba wọn.
Yatọ si pe ijọba Kwara ṣe atunkọ awọn kilaasi naa si ti igbalode, wọn tun ra awọn irinṣẹ to ba igba mu sibẹ, to fi mọ awọn aga ijokoo akẹkọọ sibẹ pẹlu.
Ọmọwe Olohungbebe jẹ ko di mimọ pe erongba gomina ni lati jẹ ki awọn akẹkọọ jẹ anfaani eto iṣejọba awarawa.
"Ko si eto ẹkọ to ye kooro, to le waye lagbegbe ile ẹkọ to ti dẹnukọlẹ. Iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fi ara jin lati rii pe gbogbo akẹkọọ ile ẹkọ ijọba ni anfaani s'awọn ohun elo ti yoo mu idagbasoke ba ilana ikẹkọọ wọn," Ọmọwe Olohungbebe sọ bẹẹ.
Bakan naa nile ẹkọ girama agba ti Olokuta nijọba ibilẹ Anfeyinoja, ijọba Kwara tun ṣatunkọ ile ẹkọ naa to ti dẹnukọlẹ pẹlu ọfiisi ọga agba, to fi mọ awọn aga ijokoo ati awọn irinṣẹ miran.
Yatọ si awọn nnkan wọnyi, ṣalanga igbalode ati omi ẹrọ igbalode ni ijọba tun ṣe sibẹ fun igbadun awọn olukọ, oṣiṣẹ ati akẹkọọ lapapọ.
Awọn ile ẹkọ miran ti ijọba tun ṣiṣẹ tuntun nibẹ ni Mount Carmel Junior Secondary School, to wa niluu Ilorin; Ansarul-Islam Secondary School to wa ni Osi; ile ẹkọ gurama ti Gbagba ati eyi to wa ji Olokonla.
No comments:
Post a Comment