Oriire nla! Gomina AbdulRazaq sọrọ lori awọn agbẹjọro agba mẹta lati Kwara to gboye SAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 26, 2025

Oriire nla! Gomina AbdulRazaq sọrọ lori awọn agbẹjọro agba mẹta lati Kwara to gboye SAN


Idunnu ati ayọ nla lo jẹ fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara lori bawọn agbẹjọro agba mẹta lati ipinlẹ naa ti wọn gboye alẹnulọrọ agba lorileede Naijiria, iyẹn Senior Advocate of Nigeria (SAN).

Gomina AbdulRazaq sọ pe iwuri nla lo jẹ foun pe awọn ọmọ ipinlẹ naa, bi wọn ṣe n gbe ogo Kwara ga nilẹ Naijiria, naa ni wọn tun n pokiki rẹ lagbaye.

Awọn agbẹjọro agba mẹta naa ni: Tairu Adebayo Esq.; Shuaib Agbarere Mustapha Esq.; ati Habeeb AbdulRahman Oredola Esq.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn mẹta yii lo wa lara awọn agbẹjọro mẹtadinlọgọta ti wọn gba igbega naa, eyi ti ajọ Legal Practitioners Privileges Committee (LPPC) kede.

LPPC sọ pe lẹyin agbeyẹwo ati iwadii kikun, wọn rii daju pe gbogbo awọn eeyan naa ni wọn kun oju oṣuwọn lati gboye tuntun naa.

Ipa ti wọn ti ko lagboole ofin ati idajọ ko ṣee fọwọ rọ sẹyin, idi ree ti wọn fi foye naa da wọn lọla.

Nigba to n fi idunnu rẹ han, Gomina AbdulRazaq ni idalọla naa lo lọ nibamu pẹlu iṣẹ ti wọn n ṣe, iwa ọmọluwabi ti wọn n ṣafihan rẹ ati ipa rere to n mu itẹsiwaju ba iṣẹ naa lorileede Naijiria lati ọdun pipẹ sẹyin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI