Kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nipinlẹ naa ni idanwo ọhun yoo ti waye, nibi ti awọn akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ti wọn fẹẹ wọ girama yoo ti kopa.
Kọmiṣanna feto ẹkọ, Ọmọwe Lawal Olohungbebe lo fidi iroyin naa mulẹ fawọn akọroyin l'Ọjọru, ọsẹ yii niluu Ilorin.
Ọmọwe Olohungbebe sọ pe gbogbo eto lo ti to, lori ki idanwo naa le lọ bo ti tọ, ati bo ti yẹ.
Siwaju sii ni Kọmiṣanna naa fidi rẹ mulẹ pe agogo mẹjọ owurọ ni idanwo ọhun yoo bẹrẹ kaakiri awọn ile-ẹkọ ti wọn ya solọtọ nipinlẹ naa.
O wa rọ awọn akẹkọọ ati alakoso ile-ẹkọ lati tẹle ilana alakalẹ eto idanwo naa.
Bakan naa lo gbe oriyin fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori bo ṣe ṣagbatẹru idanwo naa, pẹlu ikilọ pe adari ile ẹkọ tabi olukọ to ba gba owo ti ko yẹ yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ.
No comments:
Post a Comment