Ile-ẹkọ alakọbẹrẹ Adeta! Aridaju to ṣafihan ifarajin Gomina AbdulRazaq sọrọ eto ẹkọ igbalode ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 26, 2025

Ile-ẹkọ alakọbẹrẹ Adeta! Aridaju to ṣafihan ifarajin Gomina AbdulRazaq sọrọ eto ẹkọ igbalode ni Kwara


"Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq n ko ipa to jọju lati mu awọn ileri rẹ nipa mimu ayipada rere ba ẹka eto ẹkọ,' wọnyi ni ọrọ ti Oludamọran pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode, Olayinka Fafoluyi tọpọ mọ si Solace fi bẹrẹ apilẹkọ rẹ.

"O ti ṣe awọn ohun aritọkasi nipa pipese ise akanṣe alara-gbayida, gbigba awọn olukọ to yọranti siṣẹ, ati sisan owo oṣu lasiko," Fafoluyi fi kun ọrọ rẹ.

Siwaju sii lo sọ pe lara awọn akitiyan gomina ni ti kikọ ile ẹkọ igbalode ti wọn pe ni KwaraLEARN, eyi to ṣafihan ifarajin gomina lati rii pe awọn ọmọde kaakiri ipinlẹ naa ni anfaani si awọn ohun elo ẹkọ igbalode ati agbegbe ikẹkọọ to ba igba mu.

Aworan ile ẹkọ alakọbẹrẹ Adeta naa ti iṣakoso Gomina AbdulRazaq n kọ lọwọ ni yoo fi ilana tuntun lelẹ nipa akanṣe iṣẹ eto ẹkọ igbalode nipinlẹ naa.

Fafoluyi jẹ ko di mimọ pe lara agbekalẹ ti yoo wa ninu ọgba ile ẹkọ naa ni:

• Ọfiisi ọga ile-ẹkọ 
• Ọfiisi igbakeji ọga ile-ẹkọ 
• Ọfiisi nla fawọn oṣiṣẹ ati olukọ 
• Yara itọju/ile iwosan kereje
• Yara ikẹkọọ marundinlogun fawọn akẹkọọ ibẹrẹ-pẹpẹ
• Yara ikẹkọọ marundinlogun fawọn akẹkọọ lati ipele kinni si ipele kẹta 
• Yara ikẹkọọ marundinlogun fawọn akẹkọọ lati ipele kẹrin si ipele kẹfa
• Yara ẹkọ imọ sayẹnsi meji
• Yara nla fawọn akẹkọọ ayaworan (Art Rooms) meji
• Ọfiisi nla meji fawọn oṣiṣẹ ati olukọ 
• Yara ikawe nla kan
• Yara ikẹkọọ imọ ẹrọ igbalode (ICT)
• Ọgba nla to tobi fun iṣere awọn akẹkọọ 
• Ile iyagbẹ yo ba igba mu ati awọn ohun miran.

Fafoluyi wa jẹ ko di mimọ pe, nigba ti iṣẹ akanṣe yii ba pari, kii ṣe pe yoo wa lara awọn ile ẹkọ to dara julọ lẹkun aarin gbungbun Ariwa nikan, yoo tun wa lara awọn eyi to dara julọ ni Naijiria, leyi ti yoo jẹ ki awọn ọmọde ni anfaani si eto ẹkọ igbalode.






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI