Olówu pè fún àyájọ́ ọjọ́ ìṣọ̀kan Yorùbá lágbàáyé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 19, 2025

Olówu pè fún àyájọ́ ọjọ́ ìṣọ̀kan Yorùbá lágbàáyé


Olowu tiluu Owu Abẹokuta nipinlẹ Ogun, Ọba Saka Adelọla Matẹmilọla ti rọ ijọba apapọ lati ya ọjọ kan sọtọ ti wọn yoo maa ṣayẹyẹ ọjọ iṣọkan ilẹ Yoruba lagbaye.

Ọba Matẹmilọla lo sọrọ naa lasiko to n gba awọn oloye ẹgbẹ ajọ to n daabo bo aṣa ati iṣẹṣe Yoruba, iyẹn 'Foundation for the Preservation of Yoruba Culture and Heritage', lalejo ni aafin rẹ to wa ni Oke Agọ-Owu niluu Abẹokuta.

Kabiyesi alaye naa sọ pe o ṣe pataki lati maa ṣajọyọ ati ayẹyẹ ọjọ iṣọkan awọn ọmọ Yoruba lagbaye, lati le jẹ ki gbogbo agbaye mọ pe ko si ipinya tabi ẹyamẹya nilẹ Yoruba.

Ọba alaye naa gbe oṣuba kare fun ajọ naa lori awọn aṣeyọri wọn lori ayajọ ti wọn ṣe kọja, to si ni iwuri nla lo jẹ.

Kabiyesi wa pe awọn ẹgbẹ ati ajọ yooku ti wọn n gbe aṣa ati iṣe Yoruba larugẹ lati dide panupọ nipa bi ayajọ ọjọ iṣọkan ọmọ Yoruba yoo ṣe di itẹwọgba kaakiri agbaye.

O ni afojusun oun ni lati rii pe wọn ya ọjọ kan sọtọ fun ayajọ iṣọkan naa, leyi ti wọn yoo ṣe ajọyọ rẹ lọdun 2026.

Lara awọn ọmọ ẹgbẹ to wa nibẹ ni Ọmọwe Tọla Adenẹkan to jẹ akọwe agba; Ọmọwe Olugbenga Gbọlahan; Arabinrin Ọlabisi Adeẹsan ati Wolii Ọmọtọṣọ.

Nigba to n sọrọ, akọwe agba naa, Ọmọwe Adenẹkan sọ pe ifẹ ti awọn ni si aṣa ati iṣe Yoruba lo mu ki awọn da ajọ naa silẹ, lati rii pe gbogbo awọn ohun ajogunba wọn ko parun.

O ni awọn ti lọ kaakiri lati polongo iṣọkan nipa agbelarugẹ aṣa Yoruba, to si loun nigbagbọ pe gbogbo ọmọ Yoruba ni yoo dide lati rii pe afojusun awọn jẹ itẹwọgba.

Gẹgẹ bo ṣe sọ siwaju, o ni abẹwo awọn si Kabiyesi naa ni eto agbekalẹ lati ṣabẹwo idupẹ si awọn ọba alaye kaakiri ilẹ Yoruba ati ilẹ olominira Bẹnnẹ, paapaa awọn to wa sibi ayẹyẹ ọdun keji ti wọn ṣe ni gbọngan aṣa June 12 to wa niluu Abẹokuta laipẹ yii..

Lara awọn ọba to ni awọn lọ ṣe idupẹ lọdọ wọn ni Onifọnyin tiluu Ifọnyi, Ọba Rafiu Onifade Adebọwale Aniwajoye; Olu tiluu Ologo, Ọba Ismaila Ẹlẹgbẹdu Ọjẹ; Onikoyi Abẹsan tiluu Ajaṣẹ, Ọba Abdul Rahaman Aderẹmilẹkun, ati Ọba Yẹkini Adebọwale Kabiru.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI