Ọwọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti tẹ afurasi mẹrin ti wọn sọ pe wọn ko niṣẹ meji ju iṣẹ tuntun ajinigbe lọ.
Awọn tọwọ tẹ naa la gbọ pe wọn n da agbegbe ijọba ibilẹ Ifelodun laamu lati bi oṣu meloo sẹyin.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, agbegbe kan ti wọn n pe ni Shagbe lọwọ palaba ti segi.
Gbogbo awọn ti awọn ajinigbe naa jigbe la gbọ pe awọn eleto aabo gba silẹ lai farapa.
Oniruuru ohun ija oloro bii ibọn AK-47, egboogi oloro ati awọn nnkan miran la gbọ pe wọn gba lọwọ wọn.
Lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹsan, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025 ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe ipade ọna abayọ pẹlu awọn eleto aabo bii ileeṣẹ ologun, ọlọpaa ati awọn yooku.
Pataki ohun ti wọn ṣe ipade ni bi ọwọ yoo ṣe tẹ awọn igara ọlọṣa.

No comments:
Post a Comment